Ọba Samuel Odulana |
Ile
igbimọ aṣofin Abuja, ti rọ ijọba apapọ lati sọ orukọ Ọba Samuel Odulana to
doloogbe di manigbagbe ni orileede Naijiria. Wọn ni eleyii yoo jẹ imoore ati
bibu ọla fun Olubadan to jẹ laaarin ọdun 2007 si 2016 nipa awon akitiyan rẹ fun
idagbasoke awujọ. Abadofin yii ni Sẹnatọ Rilwan Adesoji Akanbi, ẹni ti n ṣoju ẹkun
Guusu Ọyọ gbe si iwaju ile.
Sẹnatọ
Adesoji ṣe alaye Ọba to lọ ba awọn babanla rẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kinni ọdun
yii (19/01/ 2016) gẹgẹ bi akikanju ọba alaye to lo gbogbo ọgbọn to ni fun
alafia ati idagbasoke ilu.
Sẹnatọ
Adesoji sọ wi pe, yoo dara ti ijọba ba le maa pe oruko ọba naa mọ ọkan lara awọn
dukia ijọba eleyii ti yoo mu orukọ rẹ wa niranti laelae fun awon iran ti n bọ
leyin.
Bakan naa, ninu apero awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin
agba to waye lỌjọbọ ọsẹ to kọja yii, gbogbo ile gbimọpọ lati yan awon aṣoju ti
won yoo lọ yoju si idile oloogbe ati gomina ipinle Ọyọ gẹgẹ bi ibanikẹdun ori
ade to papoda.
Ọjọ
kọkanla oṣu kẹjọ ọdun 2007 ni wọn wuye fun Ọba Samuel Odulana gẹgẹ bi ọba
tuntun leyin ti Ọba Yunusa Ogundipe Arapasowu gbe aafin rẹ lo salakeji.
0 comments:
Post a Comment