Smiley face

Ijamba Lassa fever wa ninu gaari lasiko yii

Desmond Oluwashola Elliot

Ni asiko ti Lassa fever n se ijamba yii. Ko ba dara ti e ba le sora fun gaari ni mimu. Awon onimoosegun ti gbe iwadii jade wi pe, opo awon eniyan ti won kan ijamba Lassa fever lo je wi pe, inu gaari ni arun naa gba wole si won lara. Ohun to si fa eleyii ko ju wi pe, eku Lassa naa ti to tabi yagbe si gaari naa ko to di wi pe won mu.

Lopo igba, awon gaari ti won gbe wa si igboro, lati igberiko tabi awon abule ni won ti n se won. Gbogbo awon iya ti won si n se gaari yii ni won ko ni akitiyan lati se itoju awon gaari yii ti eku ko fi ni raaye fenu kan-an.

Ti orisii eku Lassa yii ba si le raaye debi ti gaari yii wa, ijamba nla ni fun awon ti won ba je iru gaari bee.

Ko si isoro ninu gaari ti won te leba. Omi gbigbona yoo ti pa oro (poison) Lassa to wa ninu re.

Imoran kan ti mo tun le gba yin ni wi pe, awon ounje oniyefun te e ba ni, e da won kuro ninu apo sakasaka tabi lailoonu ti won wa, ke e maa toju won sinu ike olomori ti yoo daabo bo awon ounje naa daada. Bakan naa, e sora fun gaari mimu lasiko yii. Iku ojiji ko ni wo inu ebi wa o.   
 



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments:

  1. http://www.olayemioniroyin.com/2016/01/ijamba-lassa-fever-wa-ninu-gaari-lasiko.html

    ReplyDelete