#ogulutu
Oba ni onibara |
Ti ẹ ba jẹ ọlọja tabi oniṣẹ ọwọ, ma rọyin
lati maa tẹlẹ awọn alaye mi, eleyii to ṣeeṣe ko gba mi fun oṣu kan tabi ju bẹẹ
lọ. Nibi ni maa ti ma tẹnubọ awon ogun awure ajisa to daju, eleyii to le mu
okoowo tabi iṣẹ yin gberu koja oye yin. Lọsẹ yii, awọn onibara ni ma fi side.
Awon onibara wa ni ẹmi okoowo wa tabi
orisii iṣẹ yoowu ti a le yan laayo. Idi ni yii ti ko fi yẹ ka kọyan wọn kere.
Ohun to ṣe pataki ju lọ ni iha tabi iwa wa si awọn onibara wa. Bi onibara wa ba
ṣe pọ to bẹẹ ni okoowo wa yoo ṣe fẹju to. Iwa tabi iha wa ti a kọ si onibara wa
ni yoo si sọ bi wọn yoo ṣe pọ to lọwọ wa.
Awọn onimọ okoowo ṣe iwadii kan lọdun
2000 lori ohun to le muni padanu onibara.
Awọn idi yii ni awọn onibara ko fi wa
mọ: ida kan wọn ṣe alaisi (1%); ida mẹta (3%) won ko kuro ni agbegbe wa; ida mejidinlaadọrin
(68%) wọn kọ lati ba wa raja nitori wi pe iwa wa ko tẹ wọn lọrun; nigba ti ida
mẹrinla (14%) wọn lọ nitori ọja wa tabi iṣẹ wa ko tẹ wọn lọrun, ida mesan-an
(9%) wọn ni wọn ko ba wa raja mọ nitori won ri iru ọja wa nibomii.
Ti ẹ ba wo abajade iwadii yii daadaa,
ẹ ri wi pe, eyi to tẹwọn ju nipa idi ti awọn onibara wa ko fi pada wa lati ba
wa raja ko ju nipa iwa wa ti ko tẹ wọn lọrun lọ.
Gẹgẹ bi ọlọja, a ni lati ṣọ orisii
ede ti a n lo fun awọn onibara wa. Awọn ti wọn ba wa ra ọja gbọdọ jẹ ọrẹ wa. Bakan
naa, a ni lati ma ṣe iwadii nipa ohun ti awọn onibara wa n fẹ; awọn ohun ti yoo
wu wọn lori ti yoo si mu inu wọn dun.
A gbọdọ ma wa ni imurasilẹ lati yanju
isorokisoro ti wọn le gbe pada wa lori ọja ti a n ta fun wọn tabi iṣẹ ti a n ṣe
fun wọn.
Ẹ jẹ ki ọrọ awọn onibara wa jẹ wa
logun ju lọ. Ẹ sun mọ wọn nipa oyaya ṣiṣe. Ẹ si ri daju wi pe, o kere tan, ẹ mọ
ohun meji tabi mẹta nipa wọn bi orukọ ati nọmba ibanisọrọ wọn.
Awọn onimọ okoowo kan tilẹ ṣe alaye
awọn onibara gẹgẹ bi ọba ti ọlọja gbọdọ maa gbe gẹgẹ bi ọba Lamidi.
Lakotan, ẹ maa ṣe awọn ohun ijọloju lẹẹkọọkan
tayọ ohun ti won reti lati ọdọ yin. Awon nnkan wọn yii lo le sọ yin di ekurọ
lalabaku ẹwa loju awọn onibara yin.
Lẹyin akoko diẹ, awọn eniyan yoo ro
boya awure yin lo jẹ, nigba ti ogunlọgọ awọn onibara ba n pe le yin lori bi
igba era bo suga.
Olayemi Olatilewa ni orukọ mi, iṣẹ
iroyin ni iṣẹ mi, ilu Naijiria si ni ilu ti mo fẹran ju laye, ki Oluwa ko bukun
un lọpọlọpọ. Ire o!
0 comments:
Post a Comment