Smiley face

Ohun marun-un ti e gbodo mo nipa Lassa fever ni kiakika




  •  Odun 1969 ni won se akiyesi arun Lassa nigba ti o seku pa noosi meji kan ni ileto kan ti n je Lassa ni ipinle Borno to wa ni orileede Naijiria.
  •  Kokoro ti n fa arun Lassa yii lo wa ninu ito ati igbe ti eku Lassa ba ya jade.
  • Eku abami Lassa ti n fa arun Lassa yii, oyan merinlelogun (24) lo maa n wa ni igbaaya re yato si mejila (12) to ye ko ni.

  • Arun Lassa yii je orisii arun kan ti awon dokita pe ni “zoonotic disease”. Itunmo eyi ni wi pe, eniyan le ko orisii arun naa lati ara eranko ati eniyan to ba ni i lara.

  • Eniyan le ko Lassa nipa jije ounje ti eku Lassa ti to si tabi eyi to ti yagbe si. Bakan naa ni eniyan le ko lara eniyan to ni arun naa nipa eemi enu eni to ni, ito enu, ikunmu, omi oju tabi eje ara eni naa.

Lakotan, ile ise ijoba ti n ri si ilera, eleyii ti minisita fun eto ilera n dari, Ojogbon Isaac Adewole ni osise osibitu to ba kofiri wi pe alaisan kan ni arun Lassa, ki iru osise bee pe nomba yii fun iranwo lati odo ijoba apapo ni kiakia: 08093810105, 08163215251, 08031571667 ati 08135050005.

Arun Laasa ko ni wo inu ebi wa o.  Emi ni ti yin ni tooto, Dokita Olayemi Oniroyin.

YORUBA DUN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment