1. Odun 1969 ni won se akiyesi arun Lassa nigba
ti o seku pa noosi meji kan ni ileto kan ti n je Lassa ni ipinle Borno to wa ni
orileede Naijiria.
2. Yato si orileede Naijiria, awon orileede ti
won tun ti gburo iba Lassa ni Liberia, Sierra Leone, Guinea, ati Central
African Republic
3. Kokoro ti n fa arun Lassa yii ni eniyan le ko
latara ito tabi igbe ti o ba ti ara eku Lassa naa jade.
4. Eku abami Lassa ti n fa arun Lassa yii, oyan
merinlelogun (24) lo maa n wa ni igbaaya re yato si mejila (12) to ye ko ni.
5. Arun iba Lassa yii je orisii arun kan ti awon
dokita pe ni “zoonotic disease”. Itunmo eyi ni wi pe, eniyan le ko orisii arun
naa lati ara eranko to ba ni i lara. Bakan naa ni eniyan to ba ni naa le ko ran
elomii.
6. Eniyan le ko iba Lassa nipa jije ounje ti eku
Lassa ti to si tabi eyi to ti yagbe si. Bakan naa ni eniyan le ko lara eniyan
to ni arun naa nipa eemi enu eni to ni, ito enu, ikunmu, omi oju tabi eje ara
eni naa.
7. Ki apeere arun Lassa fever to jeyo lara eni to
ba nii, yoo to nnkan bi ose kan si meta.
Apeere eni to ba ni arun iba Lassa
8. Eni to ba ni arun Lassa yoo maa ri apeere bi
iba, yoo ma re eni naa lati inu wa, bakan naa ni ori yoo ma fo irufe eni bee.
Lopo igba, apeere ti yoo tele ni eje dida jade lati inu erigi enu, oju, ati
imu. Ni awon akoko yii, eni naa ko ni le mi daadaa mo, yoo si ma bi nigba
gbogbo. Oju re le tun wu gudugbe. Gbogbo ara ni yoo ma dun iru eni bee, to fi
mo aya, eyin ati ikun re. Bakan naa ni awon onimo isegun so wi pe, eni naa ko
ni le gboran daadaa mo. Iru eni ti arun naa ba n se, leku leyin ose meji to ba
ti n ri iru awon apere bayii lai si itoju to peye.
9. E ma fi aye gba eku ninu ile yin tabi ni ayika
yin. E se ohun gbogbo lati lewon jina tabi seku pawon.
10. Bakan naa awon ounje yin ati ohun elo ti e n
lo fun jije bi sibi ati abo gbodo wa ni imototo ati ipamo to peye.
11. Lasiko iba Lassa yii, ko ba dara ti e ba le yago
fun itoju abele nigba ti e ba gburo wi pe eni iba laago ara yin. Ti e ba tete
lo si osibitu, ti won si se ayewo to peye, ti o ba je wi pe iba Lassa ni, won
yoo tete ba yin wa ona abayo.
12. E yago fun didana sungbo ni akoko yii. Ti
eniyan ba n sun igbo, awon eku ti won fara pamo si inu igbo yoo maa tu jade
lati ma wa ibi fara pamo si. Lara awon eku yii si le je orisii eku Lassa ti n
sokunfa iba Lassa.
13. Lakotan, Ojogbon Isaac Adewole ni osise
osibitu to ba kofiri wi pe alaisan kan ni arun Lassa, ki iru osise bee pe nomba
yii fun iranwo lati odo ijoba apapo ni kiakia: 08093810105, 08163215251,
08031571667 ati 08135050005.
0 comments:
Post a Comment