*O tun fesun kan awon omo
igbimo Olubadan ati adajo agba
* “Enikeni ko to si ipo
Olubadan ayafi Oyediji” Idile Seriki
Awon idile Seriki ti gbe
Gomina Isiaka Abiola Ajimobi lo si ile ejo to gaju latari akitiyan re lati fi
onte lu iyansipo Alhaji Saliu Adetunji gege bi Olubadan tuntun. Ninu iwe ipejo
ti won fi ranse si kootu lojo Isegun ose to koja yii ni won ti ro ile ejo lati
si Ajimobi ati awon igbimo Olubadan lowo ise nipa ero ati igbiyanju won lati
yan Olubadan tuntun mii yato si Oloye Adebayo Oyediji.
Ninu iwe ipejo Ogbeni A.G.
Adeniran to je agbejoro fun idile Seriki to fi ranse si ile ejo ni oruko Oloye
Adebayo Oyediji, Oloye Olalekan Adisa Fakunle, Oloye Aside Abinupagun ati Oloye
Gabriel Amoo, ti awon je awon oloye idile Seriki, ni won ti n ro ile ejo lati
pase fun gomina, adajo agba fun ipinle Oyo, Oloye Lekan Balogun ati Oloye
Solomon Adabale lati jawo ninu ilakaka won lati yan Oloye Saliu Adetunji gege
bi Olubadan tuntun.
Lara awon ti idile Seriki
tun gbe lo si kootu ni Oloye Saliu Adetunji, Oloye Rashidi Ladoja, eni to je
gomina ipinle naa nigba kan ri, ati Oloye Eddy Oyewole. Awon yoku ti idile
Seriki tun fesun kan ni Oloye Kola Daisi, Oloye Owolabi Olakulehin, Oloye Olufemi
Olaifa ati Oloye Tajudeen Ajibola. Gbogbo awon wonyii ni idile Seriki fesun kan
niwaju ile ejo kootu to gaju eleyii to kale siluu Ibadan
Oloye Adebayo Oyedeji, eni
ti n se Osi Seriki, so wi pe, oun to mu awon gbe iru igbese yii ko ju asiri awon
agbeyinbeboje kan ti won gbiyanju lati se ohun ti ko ye nipa yiyan eni ti ko ye
gege bi Olubadan tuntun eleyii to lode si abajede ile ejo ti ojo kokanlelogun
osu kokanla odun 2008.
Ninu oro oludamoran pataki
fun gomna Ajimobi, Ogbeni Yomi Layinka, lojo
Isegun to koja, ni yoo soro fun oun lati soro lori oro naa to ba je wi pe
lotito ni idile Seriki ti pe gomina lejo.
"Oro to ba ti wa ni
ile ejo je oro elege eleyii ti a gbodo sora lati soro ba. Ohun to se pataki ni
lati duro de abaje ohun ti ile ejo ba so lori oro naa." Olayinka se alaye
ti e bee.
0 comments:
Post a Comment