*Ewa, oge, ola, Olori Wuraola lekenka
Gege bi isedale Yoruba,
ibi taa ba ti ri ori ade, awon ayaba ki i gbeyin. Eleyii lo fojuhan pelu bi
Olori Wuraola Zynab Otiti se duro gbagbaagba legbe Ooni Enitan Ogunwusi gege bi
alejo pataki nibi ayeye Igbaniwole akekoo ti Kings University to kale si
Ode-Omu nipinle Osun.
Tijotayo, tilutifon niluu
Benin fi fa Wuraola Otiti kale fun Oba Enitan Ogunwusi Ojaja II lojo kejila osu
keta odun yii (12-03-16) nibi eto ayeye igbeyawo to waye niluu Benin to wa
nipinle Edo. Bi o tile je wi pe Ooni ko si nikale nibi eto igbeyawo naa sugbon
Baba oba ati awon oloye ilu Ile-Ife soju Arole Oodua ti won si se gbogbo ohun
to ye nipa bi asa ilu Benin se laa kale. Leyin eyi ni won mu Olori Wuraola
Otiti wolu Ile-Ife nibi ogunlogo ti n duro lati woju olori tuntun laafin.
Laifi igba kan bokan ninu,
okiki aseyori Oba Enitan Ogunwusi lati da alaafia ati emi isokan pada sile
Yoruba lenu akoko perete ti Ojaja keji gori ite Odudua fi han gege bi ologbon
ati onilaakaye eda. Eleyii ti akosile re ninu itan ko le parun laelae. Ni ti
faari oge sise, Ooni asiko yii pegede. Arambara aso oge bi teye okin lomo
Ogunwusi fi n logba. Ooni Ogunwusi Ojaja keji laa ba ma pe loba onile funfun ti
n faso funfun dara oge. Awon awomo wonyii nipa Oba Ogunwusi ko je ko joniloju
nigba ti gbogbo aye foju kan orekelewa aya Oonirinsa tuntun. Sebi eni mo iyi
wura bayii la a fi i fun. Olori Wuraola pon winikinkin bi eebo. Bee lo n dan
gbinrin bi ide. Awo ara re tutu minijojo bi eja aro gidigba lodo. Funfun ehin
re ko yato si ti lekeleke oba efun. Bakan naa ni irin ese re si fi han kedere
wi pe, orekelewa ti won bi nile ola ni i se.
0 comments:
Post a Comment