Femi Solar |
Awọn Yoruba ni Satide ti yoo dun
yungbayungba, ọjọ Jimoh lapẹrẹ rẹ ti n yọju. Orisiirisii iroyin lo ti gba
igboro nipa ifilọlẹ awo orin tuntun Femi Solar. Tẹlifisan ati rẹdio o si le sọrọ
meji ki won to sọ nipa okiki, ọla ati ogo oba orin Jasa ti n bọ lona.
Boya ẹyin ko tilẹ ti i gbọ, ọjọ kewaa
osu kẹrin ọdun yii (10-04-2016)
ni omo Oladele yoo ma se ifilọlẹ awo orin tuntun rẹ to pe ni Mercy Beyond ninu
gbongan nla Genesis to wa nile Ibadan nile Oluyole Oba Saliu Adetunji (AjeOgungunniso 1).
Lara awon iwe iroyin ti won menu ba alaye
ayeye ojo naa ni NATIONAL MIRROR, CITY PEOPLE MAGAZINE, VANGUARD, PM PARROT, NIGERIAN TRIBUNE, NEWS247, THENET, DMESSAGEBLOG, DRUMBEATNEWS, NIGERIAN TRIBUNE BUSINESS NEWS WORLD, HOTDROPZ, NIGERIA SHFQNA, ati bee bee lo. Apeere yii fi n han wi pe, ayeye kan yoo waye
n'Ibadan, eleyii ti awon eniyan yoo ma fi sakawe ọrọ titi laelae.
Yato si ori ade, awon oloye laafin
ati awon ọtọkulu lawujo ti won yoo ma pejupesẹ sibi ayeye naa; aimoye agba irawọ
lagbo amuludun ilẹ Naijiria ni won yoo ma wa nikale lati ye Femi Solar si. E ma je n parọ fun yin, Olayinka Ayefele ti
setan orin, Alabi Pasuma si ti setan lati pede ara. Ti ibeji Adegbodu ba n
korin, inu emi lorin won ti wa. Mega 9'9 n ko orin atilu bọ wa lati ilu Eko wa
ka Femo Lacaster mole. A je wi pe konpitisan orin yoo tun sẹlẹ lapa kan niyen. Bi
Dele Bravo se n ju tungba bee ni yoo ma ju keneri fun awon to mọ yaayi orin
gidi. Nigba ti Taye Currency yoo maa mu nomba orin fuji nibi talujo ti gbe ki
pelu awon agba olorin to ku.
Ti gbogbo re yoo si ma sokutuwọwọ pelu
Mr Latin ti yoo ma dari eto naa bi ọkọ baalu ti n fo loke.
Eniyan ti o si lode ariya eleyii lo
miisi pupọ ju. Asọ funfun, asọ ogo, laso ariya Solar. Fidio orin Grace ti won
yoo ta legberun kan naira lọjọ naa si ni tikeeti ti gbogbo wa yoo fi wole sinu
gbongan nla ọlọyẹ tutu Genesis to wa nibadan.
0 comments:
Post a Comment