Samuel Oyindamola Olabamiji |
Ti mo ba rẹni Oluwa ọba dalọla.
Olayemi akọrin ọba emi ki i binu ori ọla.
Sebi ninu ẹran to tobi nigbo ni kunnugba ti gbe n sọla
Erin lakatabu ko ni kọja koju ẹsẹ rẹ o ma ri.
Sugbọn o wu Edua oke lo gbade fun kinihun
Kadara ò lẹjọ ninu.
Ki lo wa fẹ semi ti mo fẹ ma binu ẹni Oluwa se loore
Olayemi, emi ò ni sebajẹ eni ẹmi mimọ n ba sọrọ
Mo ti n r’akewi nilẹ yii
Orin Samuel Oyindamola Olabamiji tun se mi ni kayeefi
To ba jẹ ọgbọn ori lasan lo fi n kọrin ni
Sebi mi o ba lọ re e tunsẹ orin gidi kọ.
Ti Samuel ba n lo oye ẹda, a ba lewi rẹ ku sibi kan.
Alasepe l’ọba Oyindamọla, imisi ọba oke ni Samuẹli n lo.
ENIBAMỌNURO lewi eyi to gbede
Eni ba moore o yẹ ko dupe ore
Ẹni ba DOWNLOAD ewi eyi ko ni sai korin iyin si Jehovah.
Ti won ba bi yin wi pe
taalakewi ti n gbe akewi ẹgbẹ rẹ soke.
E wi fun won pe Olayemi
ni,
Emi lanjannu akewi ti n
wi igba ọrọ lete lai sọrọ.
0 comments:
Post a Comment