Ẹ kaabọ! Ma rọyin
lati ka IRIRI MI PẸLU ỌMỌ ONIPARAGA 1 ki ẹ to tesiwaju pẹlu apakeji to jẹ
asekagba. Ẹ le ka alaye naa NIBI.
Ti ẹyin ba ti ka
a, ẹ jẹ ka tẹsiwaju.
Iriri mi pelu omoge oniparaga 2 |
Mi o tilẹ mọ ohun to mu mi pe ọmọ oniparaga
naa pada. Emi ki i mu ogogoro, ọpa ẹyin, ale, kosi si ninu ọrọ mi. Ki ni mo wa
fẹ ra lọwọ ọmọ oniparaga?
Igba to sun mọ mi labẹ igi, Mo wi pe,
“Sẹ ẹ ni agbo iba?”
Eti asọ abiya rẹ ponkẹkẹ bi epo pupa.
Awon eri to so mọ irun abiya rẹ fẹ ẹ le ma jabọ silẹ. “E dakun, ẹ sọ mi kalẹ”
Bo se sọrọ yii jade lẹnu rẹ bu tii. Orun ẹnu rẹ dabi igba ti awon ọkọ akodọti
ba koja lẹgbẹ ẹni. Ti ehin rẹ ba pọn ko ba tilẹ daa, e wo ni kehin dudu bi ẹni in
mu taba. Olorun nikan lo moye ọjọ to ti n wọsọ orun rẹ kiri adugbo, gbogbo rẹ n
jafinkan bi ẹyin to ti dobu. Bo se bẹrẹ mọlẹ ti n ba mi tagbo, eti pata funfun
to wo han leyin rẹ. Pata funfun to wọ ti pawọda, gbogbo rẹ lo safa seti lọ, bakan
naa ni awon idọti dudu so mọ eti pata rẹ lọwọ oke.
Sasarasa ni gigirise ẹyin ẹsẹ
rẹ la bi ẹsẹ mọla. Eekanna ẹsẹ rẹ ati tọwọ ko idọti sinu bi ẹni n sise
birisope. Lapalapa ẹyin orun fẹ to osupa oju ọrun. Igba yii ni mo sakiyesi wi
pe pupa rẹ ki i se pupa gidi. Gbogbo ẹyin ika ọwọ rẹ jona bi eyin apẹ. Bakan
naa ni isalẹ oju re ti pon bi ẹni won sọ lẹsẹ loju. Atike lo n fi n gbera, oju
rẹ ti n hunjo bi arugbọ ọgọrun ọdun. Ketekete ni eniyan n wo gbogbo isan ara re
to ti di girinni, alawọ ewe, nita labe awọ ara rẹ. Gbogbo bi se n ta agbo fun
mi ni i jẹ singọọmu lẹmu pasapasa bi ẹrọ ilọgi. Ete ẹnu rẹ nipọn peeri bi awọ
maalu ti won fi n se pọnmọ funfun.
Kilode ti mo fi pe ọmọ oniparaga
gan-an? Iba o kuku se mi, kini mo fe fi agbo iba se? Se ki n se wi pe ogun lọmọ
oniparaga fi n taja? Ti ko ba je bẹẹ, bawo ni maa se maa ra ohun ti ko wulo fun
mi? Bo se ta fun mi tan sinu ọra, mo fi ọgọrun naira le e lọwọ. Bo se peyin da
ni mo sọ agbo rẹ danu sinu igbo. Olorun o ba mi yọ owo mi lapo rẹ. Nitori mi o
niidi agbo, kosi ohun ti mo fe fi agbo rẹ se. oju mi tun seesi lọ sibi
akoyinsirẹ lọwọ isale, nibi idaji ara, n se ni mo sintọ saarasa, ti mo si gba
ibi temi lọ laiwo lẹẹkeji.
THE END
Opin sinima lade yii. Mo fe ko ye yin
wi pe itan aroko lasan leyi, mi o pade ọmọ oniparaga kankan nibikibi, ki
enikeni ma fi oju onisekuse womi (erkk). Sugbọn, ohun kan ti mo n gbiyanju lati
fi han yin ni wi pe, ọpọ awon eniyan ti n da wa lọrun lokeere ni ki i se iru
eniyan ti yoo wu wa lati sunmo tabi ba sọrẹ ti a ba ni anfaani lati mọ won
daada. Aimọye ẹni iyi, ẹni ola lawujọ lo jẹ ika ati apaayan. Aimoye awon eniyan
ti won pe ara won ni ẹni Olorun lo je oniwa rirun; ti won si kun fun ọpọlọpọ ẹgbin
labẹ asọ.
Emi ma dakẹ nibi
na, lati pada si ori ojulowo iroyin gidi. Ninu iroyin tuntun to jade, njẹ ẹyin mọ
wi pe, o ti le ni miliọnu mẹta eniyan ti wọn wa sori itakun agbaye Olayemi
Oniroyin lati wa ka awon ohun ti a n gbe jade faye ri? Google lo salaye eleyii
fun mi ni kedere. To ba je ẹyin lemi ni, Olayemi Oniroyin ni emi o ba fọrọ lọ
to ba jẹ ti ipolowo oja ayelujara to munadoko.
Ẹku ikalẹ!
0 comments:
Post a Comment