Ti won ba n ka awon olorin ti ogbon, imo
ati oye won jinle nile Naijiria, ti Saheed Akorede omo Okunola ko ba si
ni ipo kinni, a je wi pe ipo keji niwon fi oruko re si.
Ogbon, imo ati oye re nipa igbe aye eda si maa n jeyo pupo ninu awon orin re.
Yato si eyi, oye Oba Orin nipa ojulowo asa Yoruba tun je ohun ti awon agba tun kan saara si lojo gbogbo.
Eleyii
lo fi je wi pe, aimoye awon akekoo-gboye ni awon ile iwe giga wa ni won
se agbeyewo awon orin ati ede Baba Suliyatu fun akanse ise asekagba
ileewe won.
Pelu
gbogbo imo Oba Nla yii, eniyan le lero wi pe iru won ko le 'niidi' imo
kankan mo. Nitori aimoye ologbon aye ni won tun ya ninu ogbon ti Big
Daddy fi n logba.
Sugbon bayii, Mr. Music tun ti pada si ile iwe giga, University of Ibadan lati tesiwaju ninu imo.
Ileewe Saint Mary's Primary School to wa l'Ajegunle niluu Eko Oba Rilwan Akiolu ni Saheed ti kawe alakobere.
Igba to setan lo lo si Amuwo Odofin High School to wa Mile 2 nipinle Eko bakan naa.
Leyin
eyi ni The Main Man pada siluu Ibadan. Eleyii to si mu gba iwe eri
National Diploma nile eko gbogbonse poli to wa nile Ibadan lodun 1992.
Leyin
akoko yii ori gbe Osupa wo ilu Amerika. Eleyii lo si fun ni anfaani
lati ko imo nipa Networking Operations ni American International
College.
0 comments:
Post a Comment