Sebi awon Yoruba ni won wi pe, ori taa fi sewe ki i kuro lorun eni taa ba dagbalagba.
Bakan naa ni ko si ifun kan ninu oromadie tawodi o mo. Ile to ba si toju eni su, ki i soro lati rin loganjo.
Bi o tile je wi pe Aare Muhammadu Buhari ti feyinti, sibesibe, abere soja ti won gun-un si wa ninu eje re titi dola.
Baba Daura ko sinu aso soja, bee lo fese meji duro wamuwamu bi ologun. O de fila sori, fila naa duro rekete bi ate. Bakan naa lo mu opa teere dani, eleyii to fi han gege bi oga ologun.
Aare lo se abewo si awon omo ologun lori papa, ni oun naa ba darapo mo won ninu aso ologun. Iroyin ba tan sibe.
E ku ikale
0 comments:
Post a Comment