Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi |
Ayafi ti a ba n tan ara wa
jẹ, ohun to daju ni wi pe, ina ede ati asa Yoruba ti n jo ajorẹyin lawujọ wa
latari ọlaju tipatipa taa gbe kari.
Ohun to n sẹlẹ yii lo mu
awon ọmọ ile igbimo asofin ipinle Eko, eleyii ti Mudashiru A. Obasa ko sodi, jigiri lati wa ọna
abayọ si.
Idi ni yii ti won fi pe
tolori-tẹlẹmu jọ si apero lati mu itesiwaju deba ede Yoruba lawujọ wa.
Lara ohun ti awon omo ile
igbimo ipinle Eko pete-pero naa ni lati maa sọ ede Yoruba pombele nile igbimo
asofin ninu gbogbo awon eto won pata. Ati lati mu ede Yoruba nipataki ni gbogbo
ile Eko ijọba to wa nipinle Eko.
Lara awon alejo to pe sibi
apero naa ni Ogbeni Rauf Aregbesola, Oba Lamidi Adeyemi III, Oba Rilwan Akiolu
ati awon eekan mii lawujo.
0 comments:
Post a Comment