Smiley face

ORÚKỌ ÀMÚTỌ̀RUN WÁ ati ÌTUMỌ

. . . #ORÚKỌ. . . . . . . . . . ̀#ÌTUMỌ

1. TÁÍWÒ/TÁYÉ:- Àkọ́bí nínú àwọn ìbejì [àbúrò].

2. KẸ́HÌNDÉ:- Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Táíwò [òun ni ẹ̀gbọ́n].

3. ÌDÒWÚ:- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé àwọn ìbejì.

4. ÀLÀBÁ:- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé ìdòwú.

5. ÌDÒGBÉ:- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé Àlàbá.

6. ÌDỌ̀HA:- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé ìdògbé.

7. Ẹ̀TA-ÒKÒ:- Orúkọ ọmọ kẹta nínú àwọn ìbejì.

8. ÌGÈ:- Ọmọ tí ó bá ẹsẹ̀ wáyé.

9. DÀDA:- Ọmọ tí irun rẹ̀ ta kókó.

10. ÀJÀYÍ:- Ọmọ tó dojú bolẹ̀ nígbà tí wọ́n bi.

11. ÒJÓ:- Ọmọkùnrin tó gbé òkun ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.

12. ÀÌNÁ:- ọmọbìnrin tó gbé ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.

13. Ọ̀KẸ́:- Ọmọ tí ó di ara rẹ̀ sínú àpò-ọmọ wáyé.

14. ÒKÈ. ọmọ tó ń dákú tí wọ́n bá da dùbúlẹ̀ fun lóúnjẹ.

15. ÒNÍ:- Ọmọ tí ó máa ń ké tọ̀sán-tòru.

16. Ọ̀LA:- Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Òní.

17. AÀSÀ:- Ọmọ tí wẹ́, tó sì máa ń ké tatata ní alẹ́.

18. ÌLỌ̀RÍ:- Ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò ṣe nnkan oṣù tó fi lóyún rẹ̀.

19. OLÚGBÓDI:- Ọmọ tí ó ní ìka ọwọ́ tàbí ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà.

20. OMỌ́PẸ́:- Ọmọ tí oyún rẹ̀ ju oṣù mẹ́san-an lọ.

21. OLÁNÍRAN:- Ọmọ tí ó mú orí wáyé tí ìyá àti bàbá sọ loruko



Orisun: Olaniran Adegboyega/Yorùbá Dùn
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment