#AyeOlabisiK @OlayemiOniroyin
Awọn Yoruba ni oju ẹni
maa la, dandan ni ki oju naa riyọnu. Itan
yii ti fi igba kan kọkọ wa lori Yoruba Dun ni odun 2011; ibẹ lati kọkọ gbe
itan naa jade. Sugbon bayii, a ti gbiyanju lati se akojọpọ itan naa ki won le
wa loju kan naa lori Olayemi Oniroyin. Sebi omi ẹko, ẹko naa ni.
Ka rosọ mọdi, ka rodi
masọ sebi kidi ma ti wa lofifo naa ni gbogbo ọgbọn tan an da.
Arabirin Olabisi K ni isele naa sele si, Olabisi K si ni awon eniyan mo si i lori Yoruba Dun nigba ti
leta naa kọkọ jade.
E je k’emi dake nibi
na, nigba ti Olabisi K yoo maa fi ẹnu ara rẹ salaye awon iriri rẹ pata sinu
leta rẹ. Sugbon ki n to dake, sekaseka ranti atunbotan. Bo o ba laye o seka, bo
o ba ranti iku Gaa ko sotito. Nitori ti ogun ba jẹ lọ, ọgbọn a maa jẹbọ.
Sii Olootu Yoruba Dun,
Inu ibanujẹ
ni mo ti n kọ lẹta
mi yii si yin. Mo padanu baba to bi mi ni kete ti mo pari ile iwe girama.
Sugbon mo pinnu lati tesiwaju ẹkọ
mi labẹ botiwukori lẹyin
iku baba mi.
Mi ò ni fẹ gba yin lakoko pupọ nipa
alaye ogun ti awon idile baba mi gbe ko iya mi, wahala ile olorogun ẹni
ori yọ o dile. Ọmọ
meji pere ni iya mi bi, obirin kan ati okunrin kan. Emi si ni obirin ti mo si
tun jẹ ẹgbọn.
Pelu agbara Olorun ati
atilẹyin iya mi ti n fi ounjẹ
tita sọrọ
aje, mo pari iwe giga mi ni nnkan bi odun mẹta
sẹyin.
Ẹlẹburukẹ
si ni Oluwa, kete ti mo pari ile iwe ni ọba
oke pese ise fun mi ni ile ise agbase se kan ni ilu Eko.
Sungbọn ìsòro
ti mo ni ni wi pe, ọga tuntun ti won sẹsẹ
gbe wa si ile isẹ wa ni dandan ni oun fẹ
ba mi sun ni tipa. O ti to osu kan bayii ti o ti n yọ
mi lẹnu.
Awada ni mo kọkọ
pe ọrọ
naa sugbọn o ti n dooto bayii. Bẹẹ ọga
yii lagbara ati dami duro lẹnu isẹ
ti ẹnikẹni
ko si ni yẹẹ lọwọ
wo.
Bẹẹ
ni mi ò setan lati fi isẹ mi silẹ
nitori ibẹ ni mo ti n ran iya mi ati aburo mi lọwọ.
Ọkọ
afesọna mi naa o ti rise kan se dabi-alara; oun
naa si n wasẹ ni. Ọkọ
afesona mi gba mi nimọran ki tun bọ
maa bẹ ọga
mi wi pe ko fi mi lọrun silẹ.
Sugbọn ọga
naa ko setan lati gbọ ẹbẹ
mi. Lowọlọwọ
bi mo se n kọ lẹta
yii, gbogbo igba lọga yii maa kanra mọ
mi, to si ma fise pami lori. Joojumọ
lo si maa dẹru ba mi wi pe, oun yoo dami duro lọjọ
kan ti mi o ba dẹkun agidi mi.
Ẹ
dakun, ẹ gbami nimọran.
Emi ni ti yin ni tootọ.
Omidan Ọlabisi
K.
0 comments:
Post a Comment