ETI TO GBỌ ÀLỌ…
Awọn Yoruba bọ, won ni eti
to gbọ alọ, o di dandan ki iru eti bẹẹ gbọ abọ. Lakọkọ na, mo fẹ dupe pataki lọwọ
Olootu Yoruba Dun ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa wi pe won ku aduroti mi, ni agbara
Edumare eyin naa ko ni ri wahala. Amin.
Gbogbo amọran yin pata ni
mo ka lẹyin igba ti Olootu se atejade lẹta mi. Bi o tilẹ jẹ wi pe lẹyin ọsẹ
meji ti mo ti kọ leta naa ni won to ba mi gbe e jade. Sibẹsibẹ naa n ko, ọpe lo
ye kin du.
Ẹ jẹ a dupe lọwọ ẹni to ri
ni to mọju, ọpọlọpọ ni o wo ibi taa wa.
Lẹyin igba ti mo ko leta
mi ranse si Olootu ni emi naa tun fi ọrọ mi lọ awon eniyan ti won sun mọ mi. Mo
ti gbe igbese saaju ki n to ri atejade leta mi lori Yoruba Dun.
Awọn Yoruba ni ọrọ ọlọgbọn
a maa jọra won, ọrọ awon omugọ lo maa n yato. Igbese ti mo gbe latari amoran ti
awon ti o sun mọ mi ko mi ko yato si ọpọlọpọ amoran ti mo ri gba lọwo awon
ololufee Yoruba Dun.
IDAHUN SI IBEERE
Sugbon saaju ki n to lo
sinu àlàyé mi toni. Awon esi kan wa to ye ki n fi ranse pada si èsì awon
ololufee mi eleyii ti mo ri ka lori Yoruba Dun.
Onigbagbo gidi ni mi, emi
ki wo asọ ti ko bo ara daada lọ si ibi ise. Bee emi ki i ba ọga mi sawada kọlọrọsi
rara. Leyin ka ki ara wa ni “ẹ kaaro sir”, ki n si se ise ti won ba gbe fun mi
lati se.
Sugbọn ohun kan lo dami
loju. A ki i mọọgun-mọọte ki iyan ewura ma lẹmọ. Ki Edumare sa gbawa lowo ẹni
to n sọni taa mọ.
KAKA KO SAN LARA IYA AJE…
Lọsan ọjọ kan ni mo tun
gbe faili wọ ofiisi oga mi yii, lo ba tun bẹrẹ ẹjo iranu ti o maa n ba mi ro ni
gbogbo igba yii.
O ni bi emi o gba fun oun
lẹrọ, ma gba fun oun lele. Mo kunlẹ pẹlu ẹsẹ mi mejeeji. Mo bẹ ẹ wi pe ko ma se
bo ti to. Pẹlu omije loju, mo sunkun kikoro wi pe ko joo nitori Eledumare to
daye ati ọrun.
Mo tun da bi ọgbọn, mo wi
fun pe ko dakun, mi o mo okunrin kankan ri laye mi.
Mo sọ fun wi pe mo ti
pinnu wi pe okunrin kankan ko ni si mi lasọ wo ayafi ale igbeyawo mi. Kete ti
mo sọrọ bayii, oga yii tun mi wo. O si so wi pe “se looto ni o ko ti mo okunrin
ri?”
Mo da lohun, mo wi pe “bẹẹni
sa”.
Okunrin yii dide lori aga
rẹ bi eni wi pe anu mi ti se pa. Lo ba wa fọwọ gbemi dide kuro nibi mo kunle
si. Lo ba si soro kẹlẹkẹlẹ si mi leti wi pe, “ti o ba je wi pe looto ni o ko mọ
okunrin ri, o si dakun ko jẹ n yẹwo boya irọ ni tabi ooto ni ọrọ naa.”
Mo tu bẹrẹ si ni bẹ oga
yii pẹlu omi ẹkun kikoro. Amo gbogbo oro mi bi igba eniyan yin agbado seyin igbá
ni. Ni iseju yii, o ti n fowo ko mi mọra bẹẹ lo n mọwọ le igbaaya mi.
Igbayii ni mo fi agidi tii
danu sori tabili rẹ. Mo pose mọ ọ. Mo si jade ni ofiisi rẹ. Inu mi bajẹ okan mi
si daru pata. Mi o si mo ẹni mo le ro temi fun.
0 comments:
Post a Comment