#AyeOlabisi5
Igba wo ni Maku ko ni ku?
Mo pinnu lati kọ leta ifisẹ-silẹ mi silẹ loju ẹsẹ. Bi ọna kan ko di
omiiran ko le la. Mo kọ lẹta mi yii, mo si fi pamọ wi pe ti o ba di ọjọ keji,
ma lo fi le ọga alagbere yii lọwọ. Nigba ti o di aarọ ọjọ keji, mo ti lo fi lẹta
naa si ori tabili rẹ ki o to de.
Leyin igba diẹ to ti de,
ikan ninu awon osise ti won tun jẹ oga fun mi wa ba mi wi pe oga patapata ni ki
n ko gbogbo ohun to wa ni ikawọ mi silẹ. Ati wi pe won ti ba accountant sọrọ wi
pe ko fun mi ni ẹto to tọ si mi.
Eyi jẹ ki n mọ wi pe
oloriburuku naa ti ka lẹta mi. Awọn ti won ko mo ibẹrẹ ọrọ lofiisi mi n bere
idi ti mo fi fẹ fisẹ silẹ, awon to mo nipa rẹ ò lagbara lati gba mi sile lọwọ
“Bashorun Gaa” to fẹ pa mi jẹ. Eni a ko le mu, Olorun laa fa le lọwọ. Emi ko
tile reti ẹto kankan lọwọ won. Nitori mo ti pa okan mi po soju kan.
0 comments:
Post a Comment