Kehinde Oladeji
O mà s̩e o: Òs̩ìs̩é̩ pápákò̩-òfúrufú kan rí ikú e lé̩yin ìbálòpò̩ pè̩lú àlè rè̩
Kí ó tó kúrò ní ibi is̩é̩ ní o̩jó̩ náà ní ó ti pe ò̩ré̩bìnrin rè̩ pe ò̩dò̩ rè̩ ni òun yóò sùn bí ó bá di alá láì mò̩ wípé oorun ìke̩yìn tí ó ma sùn nìyen.
Gbe̩ge̩de̩ gbiná fún ò̩gbé̩ni Sikiru Olanrewaju, e̩ni o̩dún me̩ta-dín-l'ogójì, àti ò̩ré̩-ìkò̩kò̩ rè̩ tí ó ń gbé ní Abule Egba nípínlè̩ Eko, nígbà tí o̩mo̩kùnrin náà jé̩pè e̩lé̩dàá lé̩yìn tí wó̩n ti ní ìbálòpò̩ tán. Olanrewaju eni ti ó ni aya àti àwo̩n o̩mo̩ síle, ni a gbó̩ wípé ó lo̩ sí ò̩dò̩ ò̩ré̩bìnrin rè̩ yìí (tí a kò tíì mo̩ orúkò̩ rè̩) ní alé̩ o̩jó̩ ìs̩é̩gun tí ó ko̩já láti lo̩ gbádùn è̩mí rè̩ mó̩jú ke̩le̩le̩.
Léyìn tí wó̩n je̩un alé̩ o̩jó̩ náà tan, àwo̩n méjèjì jo̩ ní às̩epò̩ tó ládùn dáadáa léyìn náà ni wó̩n sùn. Ìgbà tí ó di nǹkan bí ago márùn-ún ìdájí tí o̩mo̩bìnrin náà ń múra ibis̩é̩ ni ó jí o̩ré̩kùnrin rè̩ àmó̩ tí onítò̩hún ti gbèkuru je̩ ló̩wó̩ e̩bo̩ra – ó ti kú. Jìnìjìni bò ó gidigidi lórí àjálù ńlá náà.
Léyìn bí wákàti mé̩ta ti atiláawí ò dìde nílè̩ ni ó bá ké gbàjarè sí gbogbo ara ilé láti mo̩ ohun tí wó̩n sè tí ilé fi jóná. Ìgbà tí àwo̩n agbófinró dé tí wó̩n ye̩ òkú Olánrewájú wò wó̩n ri wípé kò sí àmì ìfarapa tàbí ìs̩ès̩e kankan bí ó tí ń wù kó mo̩ lára rè̩ o̩mo̩bìnrin náà sì tún te̩nu mó̩ o wípé àwo̩n dìjo̩ jé̩un pò̩ ni tí wó̩n sì tún mu omi kan náà.
À́wo̩n o̩ló̩pàá Oke-Odo, Abule-Egba ti gbé òkú náà lo̩ sí ilé ìgbókú sí báyìí wó̩n sì ti bè̩rè̩ ìwádìí kíkún lórí ò̩ràn. Kí ó tó d'olóògbé, Sikiru Olanrewaju jé̩ ò̩kan lára òs̩ìs̩é̩ pápákó̩-òfúrufú Murtala Mohammed Èkó.
0 comments:
Post a Comment