Kehinde Oladeji.
Okunrin to so aja re ni Buhari ti pada sile leyin ojo meta logba ewon.
Bi a ko ba gbagbe, ogbeni ti oruko re n je Joachim Iroko, eni ti o so aja re ni oruko aare orile ede yii, ni awon olopaa so satimo bi nnkan bi ojo bi meloo kan seyin.
Joe, gege bi won ti saba ma n pe e, ni aladugbo re fesun kan wipe o so ohun osin re ni Buhari, oruko aare ile Nigeria, ti awon olopaa si tipa bee gbe e.
Ni kanmo-n-kobo ti ole n wure ni won gbe oran omokunrin naa de ile ejo ti won si fi esun isediwo fun alafia ilu kan an.
Ile ejo majisireti ni ki won gba beeli Joachim pelu iye owo ti o to egberun lona aadota naira pelu oniduro meji.
Igbejo to waye lojo Aje to koja yii ni awon ebi okunrin naa ko ri owo itanra ti ile ejo ni ki won san ko o le. Eleyii lo si mu Ogbeni Joe di ara ogba ewon to kale si Ibara nipinle Ogun.
Joe o ni anfani àti sun ile re lati ojo naa titi di ana ti a gbo wipe akitiyan awon ebi naa so eso rere ti ile ejo si ni ki o ma lo si ile titi di ojo igbejo yoo tun pada do ohun atungbeye niwaju adajo.
0 comments:
Post a Comment