OLADEJI O. KEHINDE
Àwo̩n
o̩ló̩pàá Òkìtipupa ní ìpínlè̩ Ondo ti ń wa Goke Akinmusayo, e̩ni
o̩dún mé̩tàdínló̩gbò̩n lórí è̩sùn pé ó fi ipá ba o̩mo̩bìnrin
o̩dún mé̩rìnla kan lòpò̩.
E̩ni afurasí náà ni a gbó̩ pé ó wu ìwà
kòtó yìí nígbà tí è̩gbó̩n o̩mo̩débìnrin náà ran ní is̩é̩.
Ìs̩è̩lè̩ yìí tí ó wáyé ní nǹkan bíi aago méje sí aago mésàn-an
alé̩ àná ní ojúlé karùn-ún-lé-lógójì (45), àdúgbò Akinnubi ní
ìjo̩ba ìbílè̩ Òkìtìpupa, ìpinlè̩ Ondo ti kó ìpayà ńlá bá gbogbo
àwo̩n ará agbègbè náà.
Ìyá o̩mo̩ náà tí o̩kàn rè̩ ti dàrú gidigidi báyìí lórí is̩è̩lè̩ náà so̩ wí pé “mo ti ibi is̩é̩ dé alé̩ o̩jó̩ náà ni òun s̩e àkíyèsí wípé o̩mo̩ náà kò sí ní ìtòsí, ní èyí tí ó s̩àjèjì rè̩. Ìgbà tí mo ma bó síta pé kí ń wá a lo̩ ní mó bá a níbí tí ó tí ń jà ràpàràpà nínú ìrorà. Ìgbà ti mo bèèrè ló̩wó̩ rè̩ pé kí ló s̩e e àti wipé níbo ló ti ń bò̩, ó tiraka àti so̩ fún mi pé o̩mo̩kùnrin kan tí ó ti ń bá òun sò̩rò̩ ìfé̩ láti ójó̩ pípé̩ tí òun ò sì gbà fún un ni ó fi ipá fa òun wo̩ inú iyàrá rè̩ tí ó sì fún òun ní otí e̩lé̩rìndòdò mu kí ó tó fí ipá bá a lò”.
Gbogbo èyí ló wáyé
nígbà tí o̩mo̩dé náà ló̩ jé̩ is̩é̩ fún è̩gbó̩n òun. È̩gbó̩n
o̩mo̩ náà tí kò fé̩ kí a dárúko̩ òun so̩ wípé lóòótó̩ ni òun
rán-an láti lo̩ bá oùn gbà bátìrì fóònù òun wá ní àdúgbò náà
àmó̩ òun ò mò wípé ó ní e̩ni ti ó ń do̩de̩ rè̩.
Ìgbà
tí àwo̩n òbí o̩mo̩dé náà ti mó̩ ibi tí iná ti jó wá, wó̩n ló̩ bá
Goke ní ilé̩ rè̩ onítò̩hún ò sì sé̩ è̩sùn tí wó̩n fí kàn-án
náà. Ó ní lóòóto̩ ni òun fi ipá bá o̩mo̩n náà lò àmó̩ òun ò
mò pé ó ma dùn-ún.
Ó gbà láti tè̩lé wo̩n lo sí ilé ìwòsàn
ìjo̩ba ti wó̩n ti ń tó̩jú o̩mo̩ náà. Ìgbà tí wó̩n dé ilé
ìwòsàn, àwo̩n dókítà ní kí ó sán e̩gbè̩rún méjì náirà fún
ìtò̩jú o̩mo̩ náà. Goke ní e̩gbè̩rún-kan-ààbò̩ náírà ní ó wà
ní o̩wó̩ òun ó sì ní kí wó̩n fún òun láyé kí òun lo̩ mu èyí tí
ó kù wá nílé.
Ìyá o̩mo̩ náà tí ó pe orúko̩ ara rè̩ ní Rebecca
tè̩le e kí ó ma ba sálo̩, amò̩ ò̩rò̩ yípada nígbà tí wó̩n dé ojú
náà nígbà tí o̩mo̩kùnrin náà gbá Rebecca ní gògóńgò mú tí ó
sì já ara rè̩ gbà ló̩wó̩ rè̩ ló bá sá lo̩.
Àwo̩n
o̩lo̩pàá nàkà àbùkù sí bí ìyá o̩mo̩ náà ti s̩e jé̩ kí e̩ni
afurasí náà ó sá lo̩ kí wó̩n tó fò̩rò̩ náà tó wó̩n létí. Àmó̩
s̩á o, ìwádìí tí bè̩è̩rè̩ báyìí àwo̩n o̩lo̩pàá sì ti ń wá
gbogbo ò̩nà láti fí mu o̩kùnrin náà.
0 comments:
Post a Comment