Ninu idije ere boolu alafesegba ti Rio Olympics, abala ti awon okunrin, egbe agbaboolu Naijiria, ti jawe olubori ninu ifesewonse akoko won to waye lonii pelu bi won se feyin Japan janle pelu ami ayo marun-un (5) si merin (4).
Etebo omo Naija lo gba merin wole sanwon nigba ti Sadiq Umar gba okan ju sawon.
Sugbon ominu nko awon onwoye ere boolu Naijiria pelu bi won se ye odindi ayo merin lowo Japan, eleyii to fi n han wi pe awon agbaboolu olowo-eyin Nigeria o dile mu daada bo ti ye ki won se .
Sibesibe, awon kan ni o ti ya ju lati gba wi pe won ko koju osuwon, sebi gbogbo wa la mo isoro ti egbe naa koju saaju idije Rio Olympics ti n lo lowo ni Brazil.
Won ni oseese ki atunse waye bi idije naa se n tesiwaju.

0 comments:
Post a Comment