Kehinde Oladeji
Aajo kan ti won pe ni Network of Civil Society Organisation ni Borno ti ke gbajare lori bi ise asewo se n gbile si ni ipago ti ijoba ko fun awon ti Boko Haram le kuro labule won si, iyen ipago awon ogunlende.
Alaga aajo naa, Ahmed Shehu, ni o soro yii nigba ti o n jabo lori ayewo ti won se ni awon ipago ogunlende ariwa ati ila oorun, ni ojo isegun ti a wa yi, ni Abuja.
O ni awon odobinrin ati abileko awon ago naa ni o ti n di asewo bayii ni igbayanju ati le gbo bukata ebi won. Ninu oro re, Shehu ni "Opo awon obinrin yii ni won ti fipa balo ti won si ti pa awon miran nigba ti won segi loko, paapaa julo bi won ti n jina si abule won.
Opo odo were ni o ti di olori ebi nitori baba won tabi iya ti ku si owo Boko Haram.
Eyi ti o wa bani lokan je ju nibe ni wipe pupo ninu awon obinrin won ni o n se ise owo-lowo-eyin-nile bayii nitori ati le pese fun arawon.
Ahmed ti pe ijoba sakiyesi wipe igbese naa le se ijanba nla fun ilera ipinle naa tori orisirisi aarun ni awon omobinrin naaa le ko ti o si seese ki o tan kaakri.
Ewe, gbajumo oniroyin ipinle Borno kan ti wa soro o ni, ti ijoba ile yii ba mo wipe looto ni oro awon ogunlende yii ka oun lara, ki won aajo to n ri si iwa ibaje ati isowo ilu kumokumo wa si ipinle Borno lati wa wo bi owo ti ijoba naa lori awon na naa se n funa si. Oniriyin naa, Mohamed Alfa, so wipe ounje ti o ye ki o je ti awon eniyan ti ko nile lona naa ni awon osise ijoba kan ti te mole, ti won ti si ti n ta won gba owo re sapo ara won ti bi si n pa awon eniyan inu ago naa tobe ti o fi mu ki won maa se sina.
Aajo kan ti ki n se tijoba, NOI, ti wa kesi ijoba lati tete ri si oro naa lori orisirisi iwa to lode si igbepo awujo ti o si le sediwo fun Alafia ilu ni o n waye ni awon ipago yii.
NOI naa si ti jerii si bi awon osise ijoba se n se makaruru pelu awon nnkan itura ti o to si awon eniyan naa, bii ounje, aso, ogun ati beebee lo ti ijoba ati awon alaanu ile yii miran ti fi ranse si won.
0 comments:
Post a Comment