Yeepa! Aye mi my life |
Olayemi Oniroyin, ẹbẹ ni mo baye, kaye ma tapo sasọ ala mi. Sebi won ni aye buru, ẹnu ti won fi pe adegun naa ni won tun fi ni ko gun mọ.
Saaju asiko yii ni awon ti n se agbẹtẹru Best of Nollwyood Awards kede oserebirin Mercy Aigbe-Gentry ati alawada Okey Bakkassi gẹgẹ bi awon ti yoo dari eto naa.
Saaju asiko yii ni awon ti n se agbẹtẹru Best of Nollwyood Awards kede oserebirin Mercy Aigbe-Gentry ati alawada Okey Bakkassi gẹgẹ bi awon ti yoo dari eto naa.
Sugbon iyalenu lo jẹ bi Mercy ko se yoju si ibi ayeye ami-eye naa eleyii ti kosi so wi pe oun ko ni wa.
Lọwọlọwọ bayii, ọrọ jalajala, rederede, palapala, rọunrọun ni awon eniyan n sọ kaakiri igboro pelu bi omoge naa ko se yọju si bi ayeyey naa.
Lọwọlọwọ bayii, ọrọ jalajala, rederede, palapala, rọunrọun ni awon eniyan n sọ kaakiri igboro pelu bi omoge naa ko se yọju si bi ayeyey naa.
Gege bi akojọpọ Olayemi Oniroyin Agbaye, awon eniyan kan so wi pe, omoge naa ko dantọ, ko pegede, ko da samusamu, ko dangajia, ko pafẹẹti, ninu ede gẹẹsi ni ko fi yọju sibi ayẹyẹ naa.
"Yeepa! Aye mi my life"
Won sebi ẹ mọ wi pe ede Yoruba ni fi n se fiimu, Yoruba nikan naa lo mọ ọ sọ lẹnu. [ Olayemi, se iwọ naa le sọ oyinbo bayii? erkk]
Sugbon sa, awon Yooba ni aileja ni ita baba mi ko de hin-in. Tibinu-tibinu bi Sango oba Koso ni Mercy omoge oloju-komando fi fi ede geesi fesi pada fun awon eniyan ti won tu itukutu nigboro aye.
Sugbon sa, awon Yooba ni aileja ni ita baba mi ko de hin-in. Tibinu-tibinu bi Sango oba Koso ni Mercy omoge oloju-komando fi fi ede geesi fesi pada fun awon eniyan ti won tu itukutu nigboro aye.
“I would not speak on why I was not at BON awards or why I did not host the event. I don’t care about what anybody says. If they say my spoken English is not fluent, that is their business. I do not speak fluently yet I have hosted various awards including the City People awards. People have watched my interviews on television and they listen to me speak on my social media accounts,” alaye ti Mercy se ni yii
0 comments:
Post a Comment