Toyin Aimakhu sebi Gelede Seun Egbegbe ti jo tan, lo se lo yii oruko re pada si Toyin Abraham.
Mo ti salaye siwaju wi pe, ohun kan pataki to mu Toyin yi oruko re pada ko ju bi oruko re se n jeyo ninu awon iroyin to jade nigba ti Seun Egbegbe lo ji foonu loja.
Sugbon Seun Egbegbe tun pada se bebe, pelu ilakaka re lati lu Gambari ni jibiti owo ilu okeere.
Toyin ti gbagbe wi pe ti ogun ba jelo, ogbon a maa jebo. Gbogbo rederede to yimo oruko re lonii waye latari ainisuuru re.
Ni akoko ti ija be sile laaaarin Johnson Adeniyi ati Toyin Aimakhu, ohun ti a gbo ni wi pe Adeniyi lo se asemase.
Oun gan-an si jewo wi pe oun loun jebi Toyin, o si ro awon ololufe re wi pe ki won ba oun be Toyin.
Sugbon Toyin ko jale, a se lohun to fe se ni. Ko tojo, ko tosu, iroyin kan je jade wi pe Toyin ti bere ife pelu Seun Egbegbe.
Kaka ki Toyin nisuuru die ko to ma polongo ara re, oun gan-an fun ara re ti n gbe foto re pelu Egbegbe sori ayelujara lati fi se forifori fun oko re to ko sile, Niyi.
Aimoye foto ni Toyin fon kiri, nibi to ti n dimo Seun Egbegbe, nibi to ti fenu koo lenu. Awon nnkan bayii ti de igboro aye, kosi se fa pada mo. Oro ayelujara dabi eyin to fo, eyin to fo ko se e ko nile mo.
Ti Toyin ba tile n fe Seun Egbegbe sugbon ti ko gbe ara re le aye lowo, o si seese ki atunse si wa pelu oun ati Adeniyi nikete ti iwa oun ati Egbegbe ko bara dogba mo.
Kosi ohun ti Toyin fe se sii mo, kosi bi won se fe daruko Egbegbe ti won o ni daruko Toyin. Yoo mu u mora ni, yoo si gba a bi kadara.
Mo gbadura wi pe, Olorun yoo se oko alayo fun laipe.
0 comments:
Post a Comment