Smiley face

Itan igbesi aye Sir Shina Peters

Eniyan ti yoo pegan oosa ni o ni afin o fin to. Terin ba n lo nigbo, tigbo tiju ni i mola erin.

Papalantoro loni ireke, Ijebu loni ikokore, eni ba fe je iyan're yoo delu Ekiti. Nibi iyan ti n yoruku ninu odo gbe n joni lowo faifai. Ti a ba n so ni pa orisii agbekale orin ti n je Afro-Juju, gbogbo aye lo mo wi pe Sir Shina Peter ni oludasile Afro-juju ni ile Africa. 


Ipinle Ogun ni won bi Olushina Akanbi Peters si ni  ogbon ojo osu karun-un odun 1958.

Iwadii si fi ye ni wi pe nnkan bi omo odun meje (7) ni Akanbi ti bere si ife han si orin.

Ati igba yii lo naa lo si ti n ko nipa awon ohun elo orin bi duuru. 

Sir Shina darapo mo Ebenezer Obey gege bi okan lara awon omo leyin re. Igba to kuro leyin obey lo darapo mo General Prince Adekunle gege bi onijita. 

Kaakiria awon ile itura ati awon aye igbafe si ni egbe orin Adekunle ti n korin ni ilu Eko ni awon akoko ti Shina wa leyin re gege bi onijita ara.

Ni awon akoko ti Shina Peter wa leyin Prince Adekunle bi onijita, iwadii Olayemi Oniroyin fi ye wa wi pe ni awon igba ti ara Prince Adekunle ko ba mokun to lati sere, Sir Shina Peters lo ma n lewaju ere gege bi akorin egbe orin naa.

Gbogbo awon eniyan ni won si maa n kan saara si Shina Peters fun awon orin adidun to maa jabo lenu re nigbagbo.

Sebi baa ti waye laari, laari. Ohun ti Edua oke ba si fi ronilorun, bi idan ni i ri lowo eni.

Sugbon nigba to ya, Shina Peters fi Prince Adekunle sile lati lo da egbe orin ti won pe ni Shina Adewale sile.

Egbe orin Shina Adewale yii lo je egbe orin ti Sir Shina Peter ati Segun Adewale da sile. Awon meeji naa ni won si jo n korin papo gege bi olorin ajumo ko. 

Aimoye awo awo orin naa ni egbe orin Shina Adewale, to je apapo Shina Peters ati Segun Adewale, gbe jade, ko to wa di wi pe onikaluku sawo re lotooto. 

Sir Shina Peters da egbe orin tie sile eleyii to pe ni Sir Shina Peters and his international stars.

Ni odun 1989, Sir Shina Peters and his international stars gbe awo orin won akoko won jade eleyii ti won pe ni Ace (Afro juju series 1). 

Igba meji otooto ni awo orin yii fi gun akaso kini ninu awon awo orin to ta julo laye igba naa eleyii ti aye si n fe. 

Orisi orin Shina Peter ti won pe ni Afro-Juju yii lo je ojulowo orin juju eleyii to ni ata suesue Afrobeat ninu. Ilu Afro-juju si yara gbera nile kanmokanmo ju ilu orin juju lasan lo.

Ogbon atinuda orin tuntun yii je itewogba kaakiri laarin gbogbo eya, asa ati ilu pata.

Sir Shina Peters, baba Oluwagbemileke, a maa ta jiata ninu orin re, fere ko gbeyin ninu orin ti won pe ni Afro-juju bakan naa ni duuru tite Olushina a ma ran bi atoto arare.

Eleyii to tun wa lekenka nibe ni awon ijo Sir Shina Peters, eleyii to n mu arugbo ta kebekebe bi olomoge. 

Awon ohun ara tuntun ti Shina peter mu wo inu orin yii mu okiki kan eleyii to fi je wi pe totuntosi ni onkorin naa fi gba ami eye bi igba eye le n kore wole.

Ko wa tan sibe, gbogo ile Africa mitimiti ni akoko ti Sir Shina Peters tun ju awo orin re eleekeji sile, eleyii ti won pe ni Shinamania. (Afro-juju series 2). 

Ninu awo orin yii ni a ti ri awon orin olokiki bi "Oluwa Yo Pese", "Omo Bo" ati "Give Your Woman Chance" eleyii ti won si gbo kaakiria agbaye titi di akoko yii.

E tun wa gbo, eniyan le pe omi dudu laro, ohun to daju ni wi pe omi dudu ko le reso bi aro.

Bi eniyan paro wi pe amotekun ko yato sologini, iye eran ti won pa wale ni otito oro gidi.

Gbogbo aye ni won gba wi pe Sir Shina Peters ni oludasile Afro-Juju, lati ile yii to fi de oke okun.

Awon awo bi merindinlogun (16) ti Shina Peters gbe jade lo si duro bi ere nla ti ko ni pare lailai, eleyii ti gbogbo re si dabi oosa ajiki lawujo awon orin to gbamuse ile adulawo.

Lara awon orin ti Sir Shina Peters gbe jade pelu egbe orin re to pe ni Sir Shina Peters and his international stars ni . 

Ace Afro-juju series 1  jade lodun 1989

Shinamania lo di irawo nla lodun 1990

Dancing Time laye josi lodun 1991

Nigba ti Experience si dohun ti aye n dura lodun 1992

Awo orin Mr. President ni baba Seyi gbe jade lodun 1993

My Child dori igba lodun 1994
Kilode, ni awo orin ti  Sir Shina gbe jade lodun 1995.

Ko wa tan sibe oo, lara awon awo orin ti oko Sammie tun gbe jade ni 
Love, eleyii to jade lodun  1996

Reunion  lalewu lodun 1997

Playmate ni gbogbo aye ji ri lodun 2000

Nigba ti Happy Hour foju han lodun 2001

Pay back time jade lodun 2005

Splendour gbayii lodun 2006

D one for me ni awo orin ti sir shina gbe jade lodun 2012.

Gege bi alaye sir Shina Peters ninu orin re kan, o ni MC Hammer niluu Amerika, ise ijo ilu ati orin nise ti won, won si fi se ohun rere. "Shina Peter n ko? Bakan naa ni. Alakanbi nko? Bakan naa ni." 

Kosi anini, ise orin lo so Shina di olowo, olokiki ati eniyan iyi kiri agbaye bi goolu olowo iyebiye. 

Aimoye omo ni Afro-Juju creator bi, gbogbo won pata ni won ti soriire.

Lara awon omo re ni ni Clarence Peters, to je ogbontarigi, ilumooka ayawora nile Naijiria. 

Bi mo ba tile wa dake nibi mo ba de yii, ohun to daju ni wi pe Sir Shina Peters ko ti dake orin kiko.

Irawo to ju irawo lo si n tan,  777 is a number si n je lo nigboro, Ijo, ilu, Orin, ede, asa re sin ta kaakiri agbaye

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment