N JE E MÒ?
Ododo ni wi pe itandowe ni owe; "OWO OMODE Ò TÓ
PEPE TÀGBÀLAGBÀ Ò WO AKÈRÈGBÈ" Àmo inú ese ifa gan an ni itan náà ti sè.
Ki alaye mi o baa le yee yin, e je ki a bere pelu odu
Iwori Meji ti o
wi pe;
Owo ewe o to pepe;
Ti agbalagba ò wo akèrègbè
Isé ewe be agba
Ki o mase kò mó;
Ti agbalagba ò wo akèrègbè
Isé ewe be agba
Ki o mase kò mó;
Gbogbo wa ni a nise a jo n be ra wa....... (Wande Abimbola 1977:16)
Bi a bá wá fé tókasi itan ti o je igi eso owe yìí , báyìí ni itan náà se lo;
Alájàpá ni Iya Akanni, Atoja kan de omiran si ni o máa n ra oja. Bi
o ba ná oja Ajébamidele lonii, yóò ná Mámu lola, yoo na Aráròmi lótunla
abbl.
Ni Ojo kan, Iya Akanni kiyesi pe eran kan n ni oode won lara latari wi pe bi o se n le eran náà, ni eran yìí tun n pada. Ni Iya Akanni ba yaa dogbon si i, ko gbe ounje akanni si inu agbon ti o máa n gbé e si tele Nítorí iberu ki eran o ma baa je ounje Omo re, ni o ba nawó gbe ounje sori pepe kenu eran o ma baà to, ó si ba orò ajé tirè lo.
Elegbe pé ebi ló lé Akanni wolé láti ilé-èkó rè ni, agbara káká ni ó fi bó aso silè ki o to máa wá ounje osan re kiri inu ile nigba ti ko ri I nínú agbòn ti Iya re máa n ba a gbé ounje si. Ibi ti o ti sunupò, ni o ti tajú kán ri abo ounje re lori pepe òòdè won, ó wá Ku bi yoo se gbé e. Ori ironu bi yóò ti ri i gbé ló wà, ti o fi bo si òde, O ri baba agba ti o n fi ako okuta pón àdá.
O nà félé ki baba, o wa be baba lati dakun ba oun nawo gbe ounje oun lori pepe. Baba ni "iwa oyaju ló wu, omode kii be agba nise" Akanni toro aforijin, o si gbe apoti tisè lati gbe ounje re.
Kò pé pupo ti o jeun tan, ni baba ba pe e, pe ki o dakun ba oun yo eso oóyó nínú akeregbe nitori pe enu re kere fun owó òun. Akanni ni ki baba o má binu wi pe oun kò nii leè baa kowo bo akeregbe. Baba ba dide, o ja oré lati na Akanni fun pe o ko isé ti oun bè é. Akanni sa bo si arin aba ki egba baba o ma baa bà á.
Bàbá Àkànjî ti o ri won ni o wa da si òrò náà wi pe; "Bi e ba na omode yìí , e kan fagba re e je lasan ni, Nítorí pe gbogbo wa la jo n wulo fun ara wa.
Omo be yin nise, e kò, e wa ni komo o fi tipatikuuku se isé fun yin, ko seese Nítorí onikaluku lo ni iwulo tirè, bowo Akanni o se to pepe náà ni tiyin náà o wonu akeregbe."Baba agba gba asise re, won si fe ki elomiiran o kógbón nínú isele náà ni won fi so o di owe wi pe; OWÓ OMODE Ò TÓ PEPE, TÀGBÀLAGBÀ Ò WO AKÈRÈGBÈ.
ÈKÓ TI ÀWON ÀGBÀ FÉ KI Á KÓ:
* Iran ara eni lówó: Kágbà o ran omodé lowo, komode náà o sise fágbà.
Orisun: Olùkó Èdè Yorùbá Arb

0 comments:
Post a Comment