Awon esun bi merindinlogoji (36) ni won kefin re mo o lowo lati bi odun 2015- 2017.
Ni akoko ti ile ejo tun gbe ejo re dide lojo Jimoh to koja yii, ile ejo tun fi esun merin kun ejo re; gbogbo ejo re wa je ogoji (40).
Orisiirisii awon eniyan ti Seun Egbegbe ti lu ni jibiti seyin ni won yoju ni joojumo, awon eleri bi ogbon (30) ni won si wa pade re nile ejo lati takoo wi pe lotito ni alase Ebony Films lu awon ni jibiti pelu eri to daju.
Sugbon adajo Oluremi Oguntoyinbo ti n jokoo nile ejo to gaju nipinle Eko so wi pe, oun ko ni gba eri kankan lati enu awon eleri ti won wa tako Seun Egbegbe latari jibiti ti won lo lu awon seyin, ayafi ti awon olopaa ba pari ise olofintoto lori awon isele naa.
Leyin opin ohun gbogbo, adajo sun igbejo naa di March 24 odun 2017
0 comments:
Post a Comment