Smiley face

Iyawo Obasanjo: "Mi o ya were oo" Wahala ti sele nile Olusegun Obasanjo

Taiwo ati Olusegun Obasanjo
 
Okan ninu awon iyawo aare ile yii nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo, Taiwo Obasanjo, ti ke gbajari wi pe, ajalu nla ni yoo sele ti omo re, Abraham Obasanjo ati Tope Adebutu to je omo baba Ijebu ba fi le se igbeyawo lojo kokanla ati ojo ketala osu karun-un odun yii. 
 
Taiwo Obasanjo ti mbe gbogbo ebi ki won sun igbeyawo naa siwaju di osu kefa, o ni ti won ko ba se bee, aimoye oku ni yoo sun, ajakale arun yoo be sile, ijamba oko yoo waye, ajalu ati wahala ni yoo tele igbeyawo naa. 
 
Koda, o ti lo si ile ejo lati ma je ki igbeyawo naa waye losu karun-un ti won da sugbon ile ijo ni esun re ko lese nile.
 
Awijare iya naa ni wi pe, "Won ti so asotele fun mi wi pe, omo mi gbodo pe eni odun merinlelogbon (34) ko to le se igbeyawo. 
 
Omo mi yoo si pe odun merinlelogbon lojo kini osu kefa. Mo gba ki won se igbe iyawo fun un lojo to ba pe eni odun merinlelogbon. Mi o ya were o, mi o si ni ki omo mi ma se igbeyawo, oun ti mo n bebe fun ni ki won sun siwaju lati re ibi danu. Eyin omo Naijeria, egba mi oo" Taiwo Obasanjo
 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment