Orisiirisii ogbon
ni mo ti ko lori ayelujara. Aimoye imo ni mo si ti ni nipa akiyesi ohun to n
sele lawujo wa, eleyii ti intaneeti wa lara re. Mi o pe tan, sugbon inu ki i
sai dun lori kekere ti mo mo to n fun mi ni itura.
Lara ogbon ti mo
ko ni lati ma tako enikeni lori ayelujara eleyii to le fa ikunsinu. Mo sakiyesi
wi pe iru igbese bee ko wulo.
Opo awon eniyan
ni won sebi digbolugi aja lori ayelujara, won so ara won derujeje, gbogbo aye
ni won baja, gbogbo eniyan ni won tako. Iwonmba iriri mi fi ye mi wi pe, ko
wulo rara.
Eniyan wa ore kun
ore ni, eniyan ki i wa ota kun ota. Bi o tile je wi pe a k ii rin ki ori ma mi. Sibesibe, pele la fi
n pamukuru pele.
Kilo fa alaye mi.
Lopin ose to
koja, mo pade oga oniroyin kan ti oruko re n je Wale Ojo Lanre. Ogbeni Wale je
olootu fun iroyin irin-ajo afe fun ile ise iroyin Tribune to wa niluu Ibadan. O
je enikan ti mo feran gan-an nipa ogbon atinuda to ni ati agbekawe ise iroyin
re. Ti won ba ni eniyan danto, Oga wale Ojo Lanre ti dagbaoje ninu ise iroyin
sise. Iriri ti sarajo fun-un bakan naa ni imo re ko kere rara ise iroyin aye
ode oni.
Lopo igba, awon
atejade won lori ayelujara a maa tako ero mi. Mi o wa le so wi pe tori mo lugo
seyin komputa mi ki n ma wa tako won tabi soro alufansa si won. Kaka ti n fi se
bee, maa koja mi lo siwaju. Sebi gbogbo wa ko le sun ka kori sibi kan naa.
Ori ayelujara
lati pada, a si ti ma n jo n soro leekookan. Oga Lanre tile beere fun nomba ni
awon igba kan.
Sugbon lopin ose
to koja, nibi ayeye ojo ibi odun metadinlaadota Otuba Gani Adams nIkeja, mo
pada agbaoje yii nibe.
Nikete ti mo
kofiri re, mo sare tete lo ba. Ko oga Wale ko da mi mo doju sugbon o mo oruko
mi.
Mo gbe enu si
leti (ariwo po nibi taa wa), mo si daruko mi fun, o pada woju mi, o dimo mi terin
toyaya.
A jo takuroso
die, leyin mo wi fun won wi pe inu mi dun lati pade won. Ko je n wi dele, Oga
Wale naa ni inu awon naa dun gidigidi lati pade mi. O dabi eni wi pe won ko so
bee si mi ri. Oga wale ju mi lo lojo ori bi igba sanmon jina sile, kosi ilu tiko
ti de lagbaye, okan ninu inagije re a ma je Larinka Agbaye. Bakan naa ninu ise
iroyin, o ti je lo ki n to laju saye.
A ko pada soro mo
leyin igba naa, sugbon oju mi ko yee ma ba lo kaakiri oju agbo. Oga Wale
somoluabi pupo.
Lara kudiekudie
ayelujara ni aini ibowo fagba, aini ipaya fun eni to ju ni lo ati ipadanu
omoluabi eni. Inu mi dun wi pe oye yii ye mi. Mo ti pinnu wi pe mi o ni ni
wahala pelu enikeni, ayafi eni to ba ni wahala pelu mi. Ojo meloo la fe lo laye
ta n wewu erin.
Oga Wale Ojo
lanre, mo dupe ife ti e fi han. Boya ni mo le gbagbe ti aye mi. E seun.
0 comments:
Post a Comment