Mmmmmh! Gbogbo onise dudu aye nibo lẹ
fẹ ba ile aye ja. Sekaseka, ẹ ranti ẹsẹ mefa, ọjọ tẹ ẹ sun tẹ ò si ni ji saye mọ.
E sọfun ọdaju ẹda ko ranti Gaa Ọṣọrun. Nitori
t’ogun ba jẹ lọ, ọgbọn ko ni salai jẹbọ dandan ni.
Awon ọmọọlọmọ ni won ko lọ sòwò ẹru
lokeere. Awon ọmọ ti won o mọtun yato sosi ni won kolọ ilu ajoji sise idoti, Won
gba majesin lọwọ ẹni o niwon lo sise aséwó, isẹ ibanujẹ nibi won ko ti gbe lẹbi,
nibi won ko ti gbe lara, ti ko si senikan aa ke pe. Kilode?
Ẹ n fi ọgbọn alumonkoriyi gba awon ọmọ
wonyii lọwọ awọn obi to bi won, pelu ọrọ asọdun wi pe, ẹ fẹ ran won lowo ni. Sugbon
nigba ti won kuro labẹ iya won tan, ti won debi oju ọlọmọ ò to o, nigba ti won
dọna-ò-gbeji ti ko sibi a a gba pada sile, nibi ọmọ ti gbe n lọgun baba-yeye ti
ki i rẹni je ni “oo iwo da?”. Mmmmmmh!
Nibẹ lẹ ti bẹrẹ si ni le awọn ọmọ
wonyii sori igba bi buredi. E sọ ọmọ ẹda eniyan dọja ti won ta nigbanjo nitori
aa la ni duniyan. Bi ẹ ko tile bẹru eniyan, ẹ si bẹru ọba adakẹja bi iji ti mbẹ
lajule orun.
Jojoojumo nibadi aran fomije takoto
idi seleleya nibi won ti gbe n mu nomba leyin odi. Ika ti n gbowo ori won mbe
nibooji ti n feja tutu mogi. Sugbon Ọmọ n fesi ohun oju rẹ ri lajo ranse
sile, awon obi ni o gbọ bẹẹ eti won o si di. Obi ọmọ mbe nile reti ọmọ ti o ni pada seri wale mo. Igbeyiningbeyin
lawon obi omo to fura wi pe, ika eniyan ti n sebi ore ti sewon nijamba ona ti
jin. mmmmmm
Ero okun, ero ọsa, ẹ wa teti gbo
labare ohun to sele laba ti wa.
Iya alaanu ti ma n wa saba wa lọdọọdun
tun ti de pẹlẹbun repete. O ni awon ọmọ ti oun ko lọ lesin ni won fẹbun ohun ranse
sile.
Inu gbogbo ara ile dun sinsin bi ẹni
layin. Atagba-atọmọde ni won fo soke bi ẹni rolugbala.
Gbogbo won dunnu wi pe, awon ọmọ awon
ti n rise. Iya alaanu a tun mu lẹta arumje a fi le won lọwọ, a ni awon ọmọ won
lo ko leta ohun ranse. Opolopo omo lo tun ko lo lodun eyi.
Iya alaanu ni ile ẹkọ ni won lọ niluu nla, ti won ba pari ni won sisẹ
aje ti won pawo gidi. Eni ọmọ rẹ ti n kọse ọwọ ni ko dawoduro ko tẹle ika
eniyan rinrin-ajo aremabo. Ẹni to ye kọmọ rẹ bẹrẹ ile iwe lodun ti n bọ ni koun naa ma ba won lolu nla lọ soriire.
A lo lari, a ki i rabọ won. Gbogbo
ara ile ni i dunnu pe omo awon ko nipe kawe gboye deniyan pataki. Sugbon ise
buruku ni won fi won se. Omo oloomo laa ran nise detorutoru, omo oloomo ni won
ran nise iku. To ba leku ko ku sebi omo oloomo ni.
Won ti gbagbe wi pe, eni gbin ebu
ika, omoomo re yoo je nibe. Won ti gbagbe wi pe, oko ta so mo ope lope o pada
so moni.
Awon omo to ye ki won wa nile iwe, le
n ko lọ sisẹ gbẹmigbẹmi. E fi won sise nabi, e n fi won pawo. E mu won tipatikuuku
ki won ma baja ba omo eranko sun tori wi pe e fe dolola ojiji. Won on tun ma fi
won gbe ogun oloro koja lenu bode, ko sara ti won ki i fomolomo da. Kosi ise
buruku ti won ki i fi won se.
Bo ba wu won, won le fi won guse owo,
eleyii to ba fe tu won lasari ni won ran lajule orun. Emi eniyan ko jo awon ika
eniyan loju.
Bi won ba fẹ ko awon omoọlọmọ ni won
se bi onise Oluwa. Bi won ba mọmọ jina sokerere tan ni won pa won lekun jaye.
Lesebo lesoogun, boba laya o seka,
Sugbon to baranti igbeyin Gaa Oshorun mi o ba bee o ko gbaye serere. Ko yee ko
omoolomo rinrin ajo losigbo odaju, e yee
gba ona eburo ko ogo ojo ola ile iyi danu si koto Nitori ti ogun ba jẹ lọ,
ogbon ko ni salai jẹbo.
0 comments:
Post a Comment