Léyìn ayeye ìsìnkú ìyá àgbà bàbá mi kí àwon ègbón ìyá mi kú ìtójú mi àti ìnáwó ó sì se ìlérí láti tójú mi Gégé bí Àkórí olá rè, èyí tí Gbogbo ebí sì fowó sí.
*********************************************************************
Kò nira fún mi púpò láti bá ìyá Adébáyò gbé; Sé òrìsà àgbónjúbá ní ó jé sí mi nítorí náà gbogbo èèwo rè ni mo ti mò.
Agogo mérin òwúrò ni mo máa ń jí lójoojúmó, nígbà tí mo bá parí isé ilé tí mo dáná tán ni màá tún lo ta ojà.
Èmi ni mo máa ń kókó dé ìsò eléèlò(ata) láti ta ojà, bí ó tilè jé pé bí mo ti ń se gbogbo rè tó isó náà ni ìyá Adébáyò fi máa ń San oore fún mi , síbè n kìí banújé tàbí kárí bonú bíi tìgbín nítorí pé ìyá àgbà ti kómi pé; "ìyà tí a ò bá tíì tó kò, à á fi ayò gbà á móra ni kí ìrònú ó má baà han ni léèmò. "
Èyí gan sì ni ìdí tí púpò àwon ará ilé àti ìso wa fi máa ń lérò wí pé n kìí ronú. Béè mo máa ń ronú àmó n ò kì ń ba ara mi nínújé pèlú èrò burúkú ni.
Ní àwon àsìkò yìí, bàbá mi kìí gbélé mó, wón ti lo n sise ní ìlú Èkó kí àwon náà ó baà le máa rówó se ojúse baba fún wa.
Àìgbélé bàbá mi wá fi ààyè gba alágbède ìyá Adébáyò láti fi mí ro ohun tí ó bá wù ú,èmi náà kìí sìí dúra, mo sáà ti mò pé n kò ní ibòmíìràn tí mo lè lo mó.
Adébáyò nífèé mi(omo jéjé lòun), Adéwálé ni kìí fé rí imí mi láàtàn (Omo líle ní). Bí mo se wá ń serú ìyá tí mò ń se tomo nílé bàbá mi láì janpata yìí, Adéwálé kìí fìgbà kankan fojú ire wò mí.
KÍ WÁ NI E LÈ KÓ MI LÁTI SE SÍ ÒRÒ MI YÌÍ O?
Ìtàn yìí sì ń tèsíwájú.
© Olùkó Èdè Yorùbá Arb (2017)
0 comments:
Post a Comment