Àmọ́ bí a bá wá fi iṣẹ́ àti ipa bàbá Samuel Ajíbádé Adébáyọ̀ Àkàndé ọmọ Fálétí(Àkàndé Ọdẹ Àdàbà) láwùjọ Yorùbá wòó, a ó ní kíkú ó yọ̀ǹda wọn fún wa láyé kí á le máa kọgbọ́n sí i lára won. Àmọ́ ǹjẹ́ Àlùmúútù a máa gba irú ìpẹ̀ bẹ́ẹ̀ bí?
Ọdún 2014 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo de ilé bàbá ní agbègbè Ọ̀jọ́ọ̀ ní ìlú Ìbàdàn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ màmá mi iyì (Yínká Adébóyè) ìwé mi "Ìgba Tìrẹ Rèé" ni a mú lọ fún àníkún ìmọ̀.
Bàbá fi ayọ̀ gba ìwé yìí, wọ́n lù mí lọ́gọ ẹnu fún yíyàn tí mo yan èdè Yorùbá láàyò, wọ́n sì fún mi ní nọ́ḿbà láti máa pè wọ́n bí mo bá rí ohunkóhun tí ó rú mi lójú.
Wákàtí márùn-ún sáńgílítí ni a fi tàkòtó ìbéèrè pẹ̀lú bàbá tí wọ́n sì yànnàná gbogbo ìbéèrè wa fún wa.
Ọ̀jọ́ kejìlélógún, oṣù kìn-ín-ní 22/1/2017 ni mo tún padà wọ ilé bàbá pẹ̀lú màmá mi(Yinka Adeboye) ati aare mi (Akinkunmi Taiwo) nigba ti a se iforowanilenu wo fun won lori; "ỌṢẸ́ TÍ Ọ̀LÀJÚ Ń ṢE FÚN LÍTÍRẸ́SỌ̀ ÀPILẸ̀KỌ YORÙBÁ" àsìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yii ni mo kiyesi pe ohun baba o lọ soke bii ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ti a jo so ni 2014 ni wọ́n ti gbagbe àmọ́ pelu iranlowo màmá Faleti won ranti die.
Agba ti i fomode logbon agba ni baba Faleti. Ode ti i peran fun gbogbo ile lati je ni Akande. Bi gbogbo ode ba da bi Ajibade ni, ìbá tí sí ẹni tí yóò jẹ àsán lágbo ilé.
Baba ti se ti won, won ti ju awọ̀n sílẹ̀, KỌ́ba òkè o tọ́jú aya, ọmọ ati gbogbo iran Yoruba ti wọ́n fi sílẹ̀, kí ẹ̀yin wọn ó sì dára fún gbogbo wa. Àmín.
©Olùkọ́ Èdè àti Àṣà Yorùbá Arb(23/7/2017)
0 comments:
Post a Comment