Smiley face

Foto omo ileewe ti egungun le senu moto ni yii

Inu ibanuje ni gbogbo awon eniyan Ogbaku, to wa niluu Owerri wa lojo Aje ose yii leyin igba ti eegun kan ti oruko re n je Okorosha le omo ileewe kan pa senu moto.

Omo ileewe, omo odun merinla, n lo si ileewe laaaro Monde, ojo Aje, bo se ri eegun ni omo yii ba feregee.

Bi eegun yii se ri omode yii ti n sare ni oun naa ba sare tele lati deruba si i.

Gege bi awon ti oro soju re se so, won ni enu moto ni omo sare si nigba ti eegun un le bo.

Nigba ti eegun ri eje ti n san lo sapada, eegun sa wo aarin awon egbe re yoku enikeni ko si daamo mo.

Sugbon sa, gege bi atejade ile ise olopaa ipinle Imo, won ni awon agba adugbo ni awon yoo di ebi oro naa ru nitori bi won se fi aye gba ijade eegun lojo Aje ti opo awon eeniyan tu jade lati lo sibi ise oojo won

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment