Gbogbo ìgbìyànjú mi láti bá baba mi soro lori ipinnu mi lati lo si ile ẹ̀kọ́ giga ni o ja si pabo.
Dipo ki baba mi o ki mi laya, erin ni iya Adebayo fi mi rin nigba ti mo yoju si baba mi, ti o si ki mi nilo lati ma waa ni wọ́n lara mọ́.
Bayii ni mo pinnu lati maa se ise osu ki n le lowo niwon igba ti Bola ti se ileri lati ran mi lowo lori bi maa se wo ile-ẹ̀kọ́ gíga.
Mo n sise, mo si n fojú si iṣẹ́ aranso lodo ìyá Ayọ̀. Baba Ayọ̀ ti irinajo de ni ojo kan ni o gbe ora le mi lowo, nigba ti mo tu u wo, aso ni o wa nibe.
O si so fun mi lati má jẹ̀ẹ́ ki iya Ayo o mọ̀ nípa aso naa.
Mo ṣe ẹnu mi ní déédé ṣíbí lori ọ̀rọ̀ aṣọ ti Baba Ayọ̀ ra fun mi, eyi si dun mo baba Ayọ̀ ninu.
Yàtọ̀ si aso, oriṣiiriṣii nnkan ni baba Ayo maa n ra fun mi ti ko si han si iya Ayo.
Ode ẹlẹ́gbẹ́ ni ìyá Ayo lo ni ojo abameta kan, ni baba Ayo ba ni ki n wa ba oun yun ẹ̀yin, mo wo o loju pé, ẹ̀yìn yiyun bii ti bawo? Mo fesi pe, sà ẹ jẹ́ ki Ayọ̀ o ba yin yun un, emi fẹ́ ran aṣọ kan.
Àsiko yii ni o wa salaye pe oun ti ran Ayo nise, ki n fi okan mi balẹ̀ ko si ẹni kankan ti o le di mi lọ́wọ́.
O dide sun mọ́ mi, o di mi lọ́wọ́ mú, o tẹjú mọ́ ẹyinjú mi, emi yara gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́, ni o bá fẹ́ maa fọwọ́ wọ́ mi lára.
Mo ti i dànu, o jan idi mọ́ àga. O yara dide lati tun mi mú, emi yara sare bọ́ si ita( mo ti mọ̀ pe n o gbodo ba a ja, beeni n o lee fi ara mi sile fun)
Lati ojo yii ni emi ati baba Ayọ̀ ti di ọ̀tá ara wa. Kii fẹ́ gbohun mi anbeletase pe ki o ri mi.
Iya Ayo ri iyipada yii, o bi awa mejeeji leere ohun ti o ṣẹlẹ̀, orin ko si nnkan la jọ kọ si i létí. Ṣ
ọ́ọ̀bù ni mo wà ní ọjọ́ kan lẹ́yin oṣu mẹ́ta ọrọ emi ati baba Ayọ̀, sadede ni iya Ayo ranse pe mi lati ile, nigba ti mo wọnú ile, yara mi ni mo ba a ti o ti tu eru mi kale. Mo wolẹ̀ lati mọ ohun ti o n ṣẹlẹ̀. Ìyá Ayọ̀ ni, ọjọ́ wo lo didakuda bayii Adébánkẹ́?
Owo olowo lo wá ji ko, ti o si mo pe n o fi nnkan kan pamọ́ fún ọ nipa bí owo naa ṣe jẹ́. Alajọbí o daa laarin emi ati ẹ o.
Mo di odi lójijì, bawo ni owó se denu baagi mi, mo mọ̀ nipa owo yii ni tootọ́ amọ́ mi o mọ ibi ti iyá Ayọ̀ ko o si. Mo tẹ́wọ́ láti ṣàlàyé ni baba Ayọ̀ bá si mi ni ìgbárùn látẹ̀yìn.
O ni ;ọwọ́ ole wo lo n tẹ́? Mo ri ọ bi o se ko owo naa wole lale ana, mi o kan sọ̀rọ̀ ni. Ibo lo ko iyoku si ni ki o sọ ₦10,000 ló dín nibẹ̀.
Mo la ẹnu lati sọ̀rọ̀ amo omi lo jade loju mi. Mo kan sa n wolẹ̀ pe, emi olè! Bí iya se jẹ mí tó láyé mi mo korira olè.
Mo wẹnu ilẹ̀- wẹnu ọkọ́ mo ri i pé arin ọ̀tá ni mo tún wà lakooko yii, mo wa fi ọkan mi bẹ Ọlọ́run láti ṣí ojú àánú rẹ̀ wò mí. Iya Ayọ̀ lẹ baagi ti o fi di owo naa mọ́ mi, o ni ki n wa eyi to din nibe lọ ki n to le pada wọlé. Baagi yii ni mo mu de ita ti Ayọ̀ rí ti o sì sọ pé; baagi owo to pọ̀ daddy mi lẹ mú dání yẹn o, ki lẹ fẹ́ fi ṣe?
Mo pe e sọ́dọ̀ lati ṣalaye ohun ti o sọ ko le yé mi. O salaye bi oun se ri baagi naa lowo baba oun pelu owó to pọ̀ ti baba re si ka owo naa, amo ohun o mọ ibi ti won pada gbe sí. Mo fa Ayọ̀ wọlé(Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni àmọ́ kò ní níwájú kò ní lẹ́yìn) Ó sì tún àlàyé rẹ̀ ṣe. Ìyá Ayọ̀ wo baba Ayọ̀, baba Ayọ̀ n wolẹ̀ bi ẹni tó si owó san. Inú tèmi dùn lápákan pé o han si wọn pe n o ki n ṣe olè.
Mo ṣàlàyé ohun ti o ṣẹlẹ̀ fún Bọ́lá (Oun nikan naa lo ku ti mo foju jọ) Ó ba mi wi fun bi mi o se fi awon ẹbun baba Ayo han iya Ayọ̀ ati bi mo se di ẹnu lati sọ oro baba Ayo fun agbalagba kankan fun odidi osu mẹ́ta.
O ki mi ku ori ire pe oruko mi ti jade mo awon ti yoo wo ile eko ati wi pe eko nipa imo isegun ti mo fe gan an ni won mu mi si.
Ó gba mi ni iyanju lati wa olóye agba kan ti yoo fi ogbon agba so ohun ti o sele fun iya Ayọ̀ lai ni da ilé wọn rú nitori igba ti won yo ba ni alejo miiran, ki o ma lọ jẹ́ omo ti yoo maa gbé nnkan gbẹ̀yin ìyá Ayọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Bọ́lá, mo sìse bí ó ti sọ.
*************************
Àwọn àgbà ní; a wọ̀lú má tẹ̀ẹ́, ìwọ̀n ara rẹ̀ ló mọ̀. Ìwọ̀nba aṣọ tí mo ní ni mò n ṣe nígín, tí mo sì mú ẹ̀kọ́ mi ní ọ̀kúnkúndùn.
Lẹ́yìn ọdún kejì tí mo dé ilu Eko ni mo ti n sise ní opin ọ̀sẹ̀, beeni n ko je ki o di mi lọ́wọ́ lẹ́nu ẹ̀kọ́ mi, gbogbo esi idanwo mi ni o dara, eyi si je ki pupo ninu awon oga wa o dá mi mọ̀.
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀sọ́ọ́rọ́ ọ̀gá wa ni Ìbídàpọ̀ Fáwọlé.
Ènìyàn jẹ́jẹ́ tí kìí fa wahala ni, koda bi o ba n ko wa nikan ni a maa n gbohun rẹ̀,"A sọ̀rọ̀ bí ẹni tí kìí gbin" ni àwa akẹ́kọ̀ọ́ maa n pe laarin ara wa.
Bi a se pari ise ni ojo kefa osu Kejo ti o jẹ́ ayajọ́ ibi mi ni a bo si arin ogba ile-eko ti a si n ya fọ́tò.
Bola ni o pe akiyesi wa si moto oga Dàpọ̀(bi a ṣe maa n pe ) ti gbogbo wa si rin sun mọ́ ibẹ̀ lati kii.
A kira daadaa, o bi wa leere ohun ti a n ṣe, Tope lo fesi pe emi ni mo n se ojo ibi ti awon wa ba ya foto. Ọ̀gá Dàpọ̀ wo mi loju, o ni; se o ò fẹ́ bémi ya fọ́tò ni o jẹ́ o sọ fún mi?
Mo kúnlẹ̀ wọ̀ pé, ẹ má bínú sà, Bọ́lá lo se agbatẹrù gbogbo nnkan ti a n se yii, emi o fun ra ara mi ò pe eni kankan, e o ri pe omo "class" mi mẹ́ta lo wa nibi, awon eniyan ti Bọ́lá ló pọ̀ jù. " I'm very sorry sir".
Ọ̀gá Dàpọ̀ fà mí dide. Ó ní; Kò si wahala. Ó dúró sí ààrin wa, a sì jo ya fọ́tò. Nígbà tí ó ń lọ, ó ni ki n wa gba ẹ̀bùn ojo ibi mi ni ọjọ́ keji, o si tẹnu mọ́ ọn pé ki n ri i daju pe mo wa o. Bí ọ̀gá ti lọ tán ni Tọ́pẹ́ tẹjú mọ́ mi láì sọ̀rọ̀.
KÍN NI Ẹ̀YIN LÉRÒ PÉ TỌ́PẸ́ Ń RÒ TÓ FI TẸJÚ MỌ́ MI?
Ẹ kú ojú lọ́nà apá keje ìtàn yìí tí ó jẹ́ òpin rẹ̀.
0 comments:
Post a Comment