Ìtẹ̀síwájú àti òpin ìtàn:
Èmi àti Bólá ni a jọ lọ sí ọ́ọ́fíìsì ọ̀gá Dàpọ̀. Ó kí wa dáadáa. Ó sì rọ̀ wá lati tele oun lọ gbe ẹ̀bùn naa.
Àwa ò mọ ohun tí ó wa nibe, baagi jànànràn kan báyìí ni a gbé sínú ọkọ̀ tí ọ̀gá sí ní kí a máa júwe ilé wa bí a ti n lọ.
Emi ati Bola wo oju are wa pé, bawo ni oga se mo pe a ò gbé inu ogba ati wi pe a jo n gbe ni? Olóye ẹ̀dá ni ọ̀gá Dápọ̀, ó jọhun pé ó mọ ero wa, ó fèsi wí pé: Ohun ti a o ba fẹ́ mọ̀ nikan la ò le mọ̀, bi nnkan le gan, bo ba ti wu eniyan lati mo, wọ́ọ́rọ́ báyii leeyan ọ́ mọ̀ ọ́n. Ó wo mi lẹ́yinjú.
Mo yara tẹrí mọ́lẹ̀. Ọ̀gá Dapo gbé wa délé, ó já gbogbo ẹru fun wa, èmi pelu Bọ́lá dupe pupo; botilẹ̀ jẹ́ pé a ò mo ohun ti n be ninu ora ti o fi tobi bẹ́ẹ̀.
O wole jokoo die, o si dagbere pe oun yoo wa gbe wa ni ọjọ́ kejì, awa ni ki o mase ìyọnu, àmọ́ o ni a gbọdọ̀ duro de oun ki oun gbe wa. A sin in de idi ọkọ̀, o juwo si wa bi o se sí iná sí ọkọ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, bàtà méjì, máàgì méjì,ati awon ohun elo inu ile pẹ̀lú apo iwe kan ni a ba ninu baagi yii. Bọ́lá mu apo iwe lati ja a amo o ri oruko,"SÍ ADÉBÁNKẸ́ MI" lára rẹ̀, o na an si mi, mo gba a, mo ka a, àmọ́ ó ru mi loju.
Mo na an pada si Bola, nigba ti o ka a tan, o ní; ara ti n fu mi lati odun to kojá mi o kan sọ̀rọ̀ ni.
Sé iwọ fẹ́ so fun mi wi pe oo fura pe oga Dapo maa n fe lati ba ẹ sọ̀rọ̀ ni gbogbo igba ti a ba ri won ni? Ko si riro pẹ́ nibe o, waa fe oga ni, o kuku mọ̀ pe kii ṣe alágbèrè tabi oniwahala eda.
Inu mi ma dun si iru eni ti o fẹ́ fẹ́ yii o, iyen fi han wi pe igbeyawo wa ko ni pẹ́ si ara. Inu mi dun o, ọ̀rẹ́ mi iyawo ọ̀gá.
Mo jágbe mọ́ Bola kí ó sinmi woroworo, amo ko gbọ́, orin oga Dapo ti o kọ sí mi lẹ́tí sùn náà ló tún fi kí mi ní ojọ́ kejì.
Oga Dapo mu ileri re se, o gbe wa de ibi ti a ti nise,o si rọ̀ mi lati wa ri i ni osan ki n to lọ sílé.
Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ lalẹ̀ hù laarin wa mo si ṣalaye gbogbo irinajo aye mi fun un. Oga Dapo fi idunnu rẹ̀ han si bi mi o ṣe fi ohunkohun pamọ́ fun un nipa itan igbesi aye mi, o si ṣe gbogbo eto ti o yẹ lati fẹ́ mi níṣu-lọ́kà.
Pẹ̀lú ìkúnlẹ̀ ati ẹkún ni ìyá Adébáyọ̀ fi bẹ̀ mí ti o si n rábàbà pé kí n fojú fo àṣìṣe oun. Baba mi paapaa toro aforijin fun awon iwa ti won ti wù sí mi nitori pe bọ́yọbọ̀yọ ni igbe aye Adewale, ti Adebayo lo san die.
Iya Ayọ̀ lù mí lọ́gọ ẹnu fun suuru ati afojusun rere ti mo ni ti mo si ṣiṣẹ́ tọ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹni ti o ti lóye wí pé, "bí a o ba jìyà to kun agbọ̀n, a ò lè jẹ ayé ti o kún háhá" , àti wí pé "Òréré kii jinna ko ma nípẹ̀kun".
Osù keje lẹ́yìn igbeyawo mi ni mo pade Ọlákúnlé, ó yaa lenu lati ri mi pelu ọkọ mi nitori wi pe ko lero pe mo le de ibi ti mo de lakooko yii,ero wi pe ọmọ alata ni mi ni oun ni lọ́kàn.
O tọro àforíjìn fun iwa ibi ti o hù si mi, Ọkọ mi ni ki n mójú nù lọ́rọ̀ rẹ̀, ki n jẹ́ ki ohun tó ti kọjá ó maa bánàá lọ kí n le baà fi ayọ̀ lo òní.
Mo dáríjin Ọlákúnlé, a sì ń gbé ìgbé ayé ayọ̀. Títí di oni ni mò ń dúpẹ́ pé mo lè ní suuru lati lè de ipò dokita ti mo wa lonii, ti mi o sì jẹ́ ki ìsòro ó gbin ìkorò sí ìrìn àjò ayé mi. Ṣé ẹ wá rí i pé suuru gbè mí lọ́pọ̀lọpọ̀.
*ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ*
Ìtàn àtinúdá ni ìtàn yìí, kò sí orúkọ kankan níbẹ̀ tí í ṣe ti ẹnikẹ́ni níbikíbi, tí ó wà láàyè tàbí tí ó ti kú. Bí orúkọ tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ bá jọra wọn, ó kàn wá bẹ́ẹ̀ ni, wọn kìí ṣe ọ̀kan náà.
Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ Olódùmarè tó ni ọgbòn tí èmi ń lò. Bákan náà ni mo mọ iyì gbogbo ẹ̀yin òǹkàtàn yìí fún kóóríyá tí ẹ̀ ń fún mi,èyí tí ó ń sisẹ́ epo fún ọkọ̀ ìrònú tèmi. Mo dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, Oba òkè kò ní fi gbogbo wa sílẹ̀ nígbà kankan. Àṣe!
©Olùkọ́ Èdè àti Àsà Yorùbá (2017)
0 comments:
Post a Comment