Eku Owuro omo Karo o ji ire; ejo ki ni itumo owe Yoruba 'Ologbon di ori eja mu" ati "Gidigba osi ilekun"?— Kayode Ogundamisi (@ogundamisi) September 13, 2017
Bi Yoruba ba ni ologbon dori eja mu, omugo a di i niru.
Saaju, ko si bi eniyan se fe mu eja niru ti ko ni jabo moni lowo. Ona to rorun ju lati mu eja dani ni ki eniyan gbamu ni ori.
Yoruba a maa lo gbolohun yii nigba ti eniyan ba se afihan tabi se amulo laakaye to peye nipa sise ohun to ye.
Bakan naa ni won maa fi ta eniyan ji lati se amulo ogbon eleyii ti yoo je ki eni naa ri ohun gidi mu jade ninu igbese re.
Eleekeji, "gidigba ko silekun...", eni mu kokoro dani nikan lo le rona wole. Owe yii tun fara pe eleyii to wi pe, "abuja ko si lorun ope". Eyi tun mo si wi pe, ogbon o digi, ayafi taa ba rokun.
Yoruba maa lo gbolohun yii nigba ti won ba ri eniyan ti n fi oju ona gidi sile lati wa ogbon alumonkori da, eleyii ti opin re yoo si gunle sori ofo. Yoruba yoo je ko ye eni naa wi pe, "gidigba ko silekun."

Nigba mii, ti eniyan ko ba ni oye tabi imo lori nnkankan sugbon to fe ma sapa tabi lakaka lori nnkan ti ko nimo nipa re, Yoruba tun le wi pe, gidigba ko silekun.
Ogbon omode temi ni yii, eyin agba, e tun ba wa se afikun ogbon yin lori eleyii.
E seun
0 comments:
Post a Comment