Smiley face

OLÙTINI ÀTI ẸNI TÍ A TÌ.

OLÙTINI ÀTI ẸNI TÍ A TÌ.   

                                                            Ọba olókìkí kan wà ní ayé àtijọ́, kò fẹ́rẹ̀ sí ìlú tí wọn kò ti mọ̀ ọ́n fún ọlá àti iyì rẹ̀. Adéníkẹ̀ẹ́ nìkan ni ọmọ tí Òòsà òkè fi ta Ọba yìí lọ́rẹ pẹ̀lú bí ọlá rẹ̀ ṣe wàyàmì tó.

Àkókò tó fún Adéníkẹ̀ẹ́ láti lọ sílé ọkọ, òdodo ni pé onírúurú àwọn gbajúmọ̀ àti ọ̀tọ̀kùlú ìlú ni wọ́n fẹ́ dàna ọba, ṣùgbọ́n ohun tí ọba ń tẹnumọ́ ni wí pé òun ò lè yọ̀ǹda ọmọ kan ṣoṣo tí òun bí fún "Ọkùnrin sá" ó ní, àna òun gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó tó láti dààbò bo ọmọ òun dọjọ́ alẹ́.                                                         

Ọba ṣètò ìdíje "ìwẹdò já" fún gbogbo àwọn tí wọn fi èro wọn hàn láti fẹ́ ọmọ ọba. Ọ̀kànlénígba(201) ni gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n dúró wámúwámú lọ́jọ́ ìdíje yìí, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń gbàdúrà kí orí bá a ṣẹ é kí ó lè dàna ọba.                                              

Ọba yìí ṣàlàyé kí ìdíje ó tó gbérasọ wí pé; "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin wọ̀nyí kú ìfẹ̀, ẹ kú ìfọmọnìyàn ṣe, yoó yẹ gbogbo yín kò ní yẹ̀ sílẹ̀.

Inú mi dùn ayọ̀ mi sì kún wí pé gbogbo yín lẹ sọ wí pé ẹ ti múra tán láti wẹdò já nítorí Adéníkẹ̀ẹ́ ọmọ mi.

Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú wí pé odò tí a wà létí rẹ̀ yìí kọ́ ni ẹ ó wẹ̀ o, odò Ọlọ́ni mẹ́ta tí ń bẹ lágbàlá àfin ni ẹ ó wẹ̀.

Ẹni tí ó bá sì lè wẹdò náà já ni yóò fẹ́ Adéníkẹ̀ẹ́ mi, yàtọ̀ sí èyí, n ó dàá ilé àti ọ̀nà mi sí méjì fún Olúwarẹ̀. Ó yá ẹ gbéra, ẹ jẹ́ kí á lọ sí àgbàlá àfin láì fi àkókò ṣòfò. Ẹ ṣeun o"     

                                              
Nígbà tí wọn yóò fi wọ inú ààfin, àwọn Olùdíje tí wòn ń du ọmọ ọba ti dín ku ọgọ́rin (80).

Ìyàlẹ̀nu ńlá gbáà ni ó jẹ́ fún ọba pé nígbà tí wọn yóò tún fi rìn gbẹ̀rẹ̀ dé àgbàlá ní ibi tí odò Ọlọ́ni mẹ́ta wà, àwọn Olùdíje tún ti dín ku ọgbọ̀n (30).

Ọ̀tún ìlú ni ó wá fi ọkàn Ọba yìí balẹ̀ láti máṣe jáyà, ó ní, bí ọ̀nà bá ṣe rí la ṣe é tọ̀ ọ́.

Nítorí náà kí Ọba ó gbà pé ọ̀nà gbòòrò ti di tóóró nù un kí àwọn ó sì yáa fi ọgbọ́n tọ̀ ọ́ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀tún pe àwọn Olùdíje sí gbangba, ó ní kí wọn ó tò létí odò, ó wí pé; "Ní kété tí kàkàkí ọba bá ti dún ni kí ẹ kánlu odò, àwọn olóyè kan wà ní òdìkejì odò lọ́hùn_ún láti mú ẹni tí ó bá gbègbà orókè. Ẹ múra gírí, kàkàkí ò ní pẹ́ dún o".                                                                       

Ní kété tí kàkàkí dún, ẹyọ ẹnìkan péré ló kán lu omi nínú gbogbo àwọn ọgbọ̀n tí wọ́n dúró sí etí odò.

Dípò kí àwọn mọ́kàndínlọ́gbọ̀n yòókù ó kánlu omi bí wọ́n ṣe gbọ́ dídún kàkàkí, ẹ̀yìn ni wọ́n sún sí bí àgbò tí ó fẹ́ kàn.

Ẹnikan ṣoṣo tí ń jà fitafita láti móríbọ́ dé òdìkejì odò ni Ọba, àwọn ìjòyè àti gbogbo ìlú ń wò tí wọ́n sì ń kansárá sí i.                                         

Torin,tìlù àti ijó ni wọ́n fi pàdé rẹ̀ lódìkejì, ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún gbogbo wọn nígbà tí Ọkùnrin tí ó wẹdò já náà jáde tí ó tẹjúmọ́ àrin èrò tí ó sì wí pé; "TAA LÓ TÌ MÍ?                                        

Kábíyèsí àti àwọn ìjòyè wo ojú ara wọn pé, ÀṢÉ KÒ MỌ̀ Ọ́N MỌ̀ BỌ́ SÍNÚ OMI. Ọ̀tún ló wá yànnàná ọ̀rọ̀ pé bí ilé ayé ṣe rí lẹ rí un Kábíyèsí.

Bí kò bá sí Olùtini kìbá tí sí Olúborí, ojú kan náà ni gbogbo ẹ̀dá ìbá wà bi adágún omi.

Olùtini le ti ni sẹ́nu ikú, ẹni tí a tì ló gbọ́dọ̀ jà fitafita láti là, ìjà fitafita ẹni tí a tì láti móríbọ́ ni yóò sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di ẹni iyì àti ẹ̀yẹ bí i ti arákùnrin yìí.

O kú oríire o! Ẹni ti ó tì ọ́ sẹ́nu ọ̀ni ò mọ̀ pọ́nà ọlá,ọlà àti òkìkì ni òun tì ọ́ sí,mo mọ̀ pé bí onítọ̀ún bá mọ̀ ni, kò ní tì ọ́. 

OHUN TÍ MO FẸ́ KÍ Á DÌ MÚ.

Gbogbo wa la nílò Olùtini kí á baà le tẹ̀síwájú. Bí Olùtini bá tì yín, ẹ máṣe banújẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ bẹ Olọ́run, kí ẹ sì jà fitafita láti bọ́ lẹ́nu ọ̀ni tí ó tì yín sí tóbẹ̀ tí ìtìjú àti àbùkù yóò fi jẹ́ ti Olùtini, tí iyì àti ẹ̀yẹ yóò sì jẹ̀ ti ẹni tí a tì.  Iwájú ni a ó máa lọ o!                                                                      

©Olùkọ́ Èdè àti Àṣà Yorùbá Arb (2017)

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment