Lọ́jọ́ tí Buhari ṣe ọjọ́ ìbí, àìmọye gomina ni won peju sile àgbàrá Abuja.
Won ki Buhari tẹrin-tẹyẹ. Awon kan tilẹ ń kí ni oriki ìdílé tí Buhari fún ara rẹ kò mọ. Bí wọn ṣe ń pè ni SaiBaba, awon kan pé l'Ọganla olórí pipe. Won fẹ́ lójú, won fẹ́ lẹ́nu, bí won se n bá a lọ́wọ́ ni won dimọ gbàgìgbàgì.
Awon gómìnà kan tilẹ n jo bi òkòtó láti ṣe afihan bí wọn ṣe nifẹ Buhari to.
Bi Muhammadu Buhari ṣe jẹ́ enikan tí kìí tètè rẹrin, ko mọ ìgbà tó bù serin. Erin gba gbogbo ẹnu rẹ tan- erin-arin-yọmi-loju.
Awon kan kọ sínú káàdì ẹ̀bùn ọjọ́ ìbí wí pé, ayé ń fẹ Buhari, won ni Ọlọ́run yọnu si pupọ, wọn ni àwọn oosa ilé adulawo pata ni won bẹ leyin rẹ bí iké.
Ko si iru ọ̀rọ̀ aládùn tí wọ́n ko sọ tán. Díẹ̀ lo ku ki won pe ni Ubangiji.
Ṣùgbọ́n ṣe Buhari ni wọn fẹ ni? Buhari kọ, ipò, agbára, òkìkí, iyì, ọlá Buhari ni won yọ mọ.
Ti àwọn nǹkan yìí kò bá sì nibẹ, bí ọ̀pọ̀ wọn ba rí Buhari wọn lé títọ sì lára lai wo tí ọjọ́ orí rẹ. Kosi òtítọ́ mọ láyé. Ẹ̀rín kìí ṣèfẹ́. Ti ayé bá ń fẹ́ ọ má dunnu ju. Ma rora, iro laye. Òtítọ́ kò sí níbi kankan.
Ire o!
#Buhari@75
0 comments:
Post a Comment