Smiley face

Àwọn èdè tuntun nínú èdè Yorùbá

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún bẹẹ lorisirisi ọ̀rọ̀ tuntun ń jẹyọ nínú èdè Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ kan tí gbilẹ láwùjọ wá lónìí eléyìí tí kò sì nínú èdè wa ni nnkan bí ogún tabi ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn.

Lára irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹẹ ni "gbajuẹ" eléyìí ti wọn lo dípò "jìbìtì". A kò lè sọ pàtó ọdún tí ọ̀rọ̀ yii jẹ́yọ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ si ni kíyèsí ni nnkan bí ọdún 1992 sókè .

Bákan náà ni oro bí "Jeunsoke" to gbilẹ láàrin ọdún 2001 sì 2002. Jeunsoke ni wọn lo láti fi dípò oro bí àṣeyọrí tàbí aluyọ.

Bí ó tilè  jẹ wí pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ má ń jẹyọ bí àṣà dídá latara olaju, amuludun, akitiyan oselu sise àti bẹ́ẹ̀ bẹẹ lọ, ṣùgbọ́n pípẹ́ tí ewé wọn pẹ lára ọṣẹ ti ń sọ wọn dọṣẹ.

Pupọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí di ohun tí wọn lo gẹ́gẹ́ bi èdè  joojumọ báyìí nílé ìjọsìn, ìpàdé, kíláàsì, ninu litiresọ, àti àwọn agbegbe àwùjọ yoku.

Inú mi yóò dùn láti mọ bóyá ẹni àtúnṣe sì ohun tí mo ṣe àlàyé rẹ sókè yìí tàbí àfikún nípa àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tí ẹ ṣe àkíyèsí rẹ láwùjọ wá. Ẹ seun

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment