A ki rọ’ ba fin la lẹ de Ọyọ O ya ẹ jẹ a lọ ree ki Alaafin
Olayiwola ọmọ Adeyemi ọkọ Abibatu.
Lamidi ọmọ a jowu yọ kọ lẹnu
A bi Ila tọ-tọ lẹhin Pan-du-ku bi soo ro
Ibi ti wọn ti ni ki Olowo gbowo
Ki Iwọfa sọ tọ wọ rẹ nu,
Ṣe ko le ba di’ja, ko le ba daapọn
Ki Ọba Alade le ri n jẹ,
Ọyọ mọ laafin ojo pa Ṣẹkẹrẹ, ọmọ Atiba
Babalawo lo difa, pe ibiti ilẹ gbe yọ ni aye wọn,
Ọyọ ode oni, ni Agọ-Ajọ, Ọba lo tun tẹ, laye Atiba Ọba, Adebinpe O Ṣakẹkẹ, Adebinpe, eji ọgbọrọ, Alade lẹyẹ Akande, Ọba, aji boyinbo seleri,
Ọba taa ri, taa ka po la po, taa kọ fa, lọ fa,
Taa ka pata, lo ri Apata, Bẹmbẹ n ro, imulẹ lẹhin agbara,
Ọdọfin ijaye, o jẹ du ro de la kanlu, ọmọ a ja ni lẹ ran gan-gan,
Eji ọgbọrọ,Alaafin Atiba, Ọba lo ko wo jẹ,
Ko to dori Ọba to wa lo ye,
Layiwola ọmọ bibi inú Adeniran
A ji se bi Ọyọ laa ri, Ọyọ o jẹse bi baba eni kan-kan Pin ni si lọ ‘mọ Erin t’ n fọ la ya ‘gi,
Ọyọ lo ni ka rin, ka san pa, ka gbẹsẹ, ko yẹ yan,
Oko ala kẹ, ọmọ a fo ko ra lu,tí wọn o ba mọ Erin,
Se wọn o gbọ‘hun Erin ni,
A ji sọ la, ọmọ a jo wu yọ kọ lẹ nu.
0 comments:
Post a Comment