Àìrìn jìnà laì rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Tí ènìyàn bá rìn títí yóò ribi tí wọn ti ń fodó ìbílẹ̀ jẹun.
Alhaji Lamidi Olaegbe Atinsola Tatalo Alamu tí gbogbo ènìyàn mọ sì Tatalo Alamu je olórin to gbajumọ ni àkókò ti ẹ ní ìlú Ìbàdàn.
Ṣùgbọ́n ohun tí mo fẹ́ mẹnuba ni bí ó ṣe ń jẹ "Tatalọ" gẹ́gẹ́ bí orúkọ.
Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Ibadan, Lamidi jẹ enikan to fẹran ọbẹ̀ gbegiri pupọ.
Yàtò sì eléyìí, ó jẹ́ ẹnikan to fẹ́ràn ata jíjẹ nínú oúnjẹ nígbà tó wà lọ́modé.
Tí gbẹ̀gìrì bá ti di ọjọ́ kejì, ní Lamidi yóò máa sọ fún ìyá rẹ wí pé kò tún ata lọ sí gbẹgiri ana kò tún lè tá yẹ́ríyẹ́rí sii lẹ́nu.
Ìgbàgbọ́ rẹ ni wí pé, ata yóò ti má fẹ parẹ́ nínú gbegiri ọjọ́ kejì.
"Mọọni, ẹ tún ata lọ sí gbegiri" tí Lamidi má ń pariwo nígbà náà lọ je ki wọn maa pe ni "Ta-ta-lọ" eléyìí to tún mo sì "tún ata lọ"
Òópó Yọ́ọsà ni agboolé Tatalọ Àlàmú nílùú Ìbàdàn.
E ku ojú lọ́nà fún akojopo ìtàn igbe ayé àgbà olórin, Tatalọ Alamu, eleyii tó mi Ìbàdàn àti Ìlú Èkó jìgìjìgì nígbà ayé rẹ.
0 comments:
Post a Comment