Oro tún ti gba ibòmíràn yọ. Olóòtú àgbà fún ileese ìròyìn Sahara Reports, Omoyele Sowore tí korò ojú bí bí àwọn adari ṣe peju láti ṣe ìgbéyàwó àwọn ọmọ gómìnà to wáyé nílùú Kano ṣùgbọ́n tí wọn fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ọmọ ará ìlú tí àwọn Boko Haram jigbe salọ.
Yàtò sì àwọn ọmọbìnrin Chibok eléyìí ti wọn kò ti rí wọn sajọ tán. Àwon omo iléèwé Dapchi, ọmọbìnrin bí àádọ́fà (110) ni Boko Haram tún jigbe salọ laipe yii.
"Won ko bìkítà nípa wa. Nígbà ti àwọn ọmọ ti wọn se ìgbéyàwó, àwọn ọmọ ti wá di àwátì" Ogbeni Sowore lọ kò eléyìí lórí ẹ̀rọ Twitter ayélujára.
Ṣùgbọ́n sá, nínú ọkàn nínú àwọn atejade to Ogbeni Femi Adeshina, oluranlowop nípa ìròyìn fún Aare Buhari, so wí pé, ijọba àpapọ̀ kò sún lórí oro naa.
Àti wí pé ilé ìṣe ọmọ ológun ilé yìí tí bo soju ìṣe láti rí wí pé àwọn ọmọbìnrin tí wọn jiko ni Yobe náà padà wálé.
0 comments:
Post a Comment