- 4 -
Àdìsá gbá owó tìdùnnútìdùnnú, ó dà a sí àpò, ó sin Balógun sí ònà, bó se padà dé ó ké sí Àjoké àti ìyá rè láti fi tó won létí.
Àdìsá sàlàyé ohun tó gbé odidi Balógun ìlú àwon wá sí ilé òun àgbè lásánlàsàn.
Àdùnní ní kò burú oríire náà ni, sebí ìdùnnú òbí ni k’ómo ríbi ire so erù rè kà, bí wón bá sì mú baálè Alákùko tán, tí wón mú òtún àti òsì baálè, Balógun ló kàn, nínú gbogbo àwon gbajúmò ìlú, ti Balógun yàtò, yàtò si pé arewà okùnrin ni ó tún rówó túnra se èyí sì mú kó mó on dá òpòlopò obìnrin ìlú won lórùn, bí ó tilè jé pé ìyàwó méta ní n be lóòdè Balógun, kò sí èyí tí kò sí àwò ìtójú lárá rè, bí irú Balógun bá wá toro omo àwon láti fé, kò si òun tó burú níbè.
Níse ni inú n bí Àjoké gbogbo bí ìyá àti bàbá rè sé n dá a tí wón n gbè é, kò fèsì kankan, ó n rò ó nínú rè pé ó níláti jé pé àlá ni òun n lá, ìgbá tí ìyá rè fi owó tó o tó ní kín ló rí so sí òrò tó wà nílè yìí ló tó mò ón lóràn.
Àjoké bèèré o ní “Sé bàbá Balógun wá toro mi f’ómo won ni àbí fúnra won?”
“Irú ìbéèrè wo l’Àjoké a n bèèrè yìí? Sebí gbogbo ìlú ló mò pé Balógun ò l’áròólé, Adétúlé ni gbogbo àwon omo rè, bí elédùá bá sì wá bá o se e, kí Balógun tara re ní Adékúnle”
“A jé pé Àjoké mi soríire nùn-un”
Àdùnní kín oko rè léyìn.
Àjòké dáké lo gbárí, okàn rè dàrú, inú rè sì bàjé, ó rò ó pé irú ayé wo lòun wá wà yìí, sé tí elédùá ò bá tiè ko fáfitì mó òun tó jé pé oko níní náà bá ni òrò òun je mó, sé irò baba òun ló wá ye kó jé adé orí òun, egbé n bí wón kán?
Àjoké dáhùn ó ní “Èmi sírú bàbá Balógun un, egbé irò baba mi, léni té n lo ‘é' fún tí n lo ‘ó' fún yín, èmi ò lè fé egbé baba mi o”
“Ta legbé baba re? sé Tìámíyù lo pè légbé mi, igiimú ò wa jìnnà órí, oyè tó mò je mò la fi n bòwò rè, ní Tìámíyù tó je ojú mi n wón se bí i, kódà ó kojá péyàá mi pòn mí léyìn lo’bi ìsomolórúko rè, esè ara mi n mo fi rìn débi mo gbé je’kà ìkómo rè” Àdìsá sàlàyé fún Àjoké.
“E wò ó, e è bá à je okà rè, kò bá à sì je okà yín, ohun tó dá èmi lójú ni pé n ò lè fi arúgbó se adé orî” Àjoké sòrò ó sì fìbíní kúrò níwájú àwon òbí rè. Inú bí Àdìsá fún ìwà àfojúdi tí omo rè wù ó sì bèrè sí ni lérí lórísìírísìí, Àdùnní rò ò pé kó má se fi ìwà Àjoké se ìbínú pé ó bá a lójijì ni àti pé bó sé má n kókó rí lára àwon òdómobìnrìn òde òní nìyen. Àdùnní wá se ìlérí láti bá omo rè sòrò.
* * * * *
Adérìnólá wà ní yàrá ìgbàlejò rè, ó fi èyìn tì lórí àga tìmùtìmù, ó kà esè sórí tábìlì kékeré iwájú rè, otí elérìndòdò wà ní orí tábìlì tó wà légbèé rè, ó gbé otí náà, ó sé díè sí ònà òfun, ó tejú mó ìwé ìròyìn aláròyé Yorùbá tó n kà, bí o sé n fi ojú kà á ló n sòrò sókè.
“Only God can save us in this country, àbí e è wa rí nnkan ni, níbi tí òpò omo mèkúnnù ti kàwé tí won ò rísé, tí àwon tó rísé gan ò ri owó isé won lásìkò ni ejò àti òbo lásánlàsàn n gbé owó mílíònù náírà mì bí oúnje, sé àwa là n tanra wa ni? àbí àwon olósèlù yìí ló n tàn wá?”
Ó gbó tí aago enu àbáwolé yàrá ìgbàlejò dùn ó béèrè pé,
“Ta nì yen?”
“Tósìn ni sir” Tósìn, akòwé rè dáhùn láti ìta.
“Tósìn? Wolé, ìlèkùn wà ní sísí” Tósin wolé ó tè láti kí ògá rè.
“E káàsàn sir”
“Báwo ni? Mo mà rí e nílé mi, sé kò sí?
“Kò sí sir, ayò ni”
Dérìn nawó sí àga fún Tósìn látí jókòó, Tósìn jókòó ó sì yo káàdì ìpèsáyeye ìgbéyàwó rè jáde nínú báàgì rè, ó nà án sí ògá rè, ó sì sàlàyé fún wí pé òun kò fé fún un níbi isé kó má dàbí àfojúdi ló jé kí òun mú un wá sílé fún un.
“Good, o kú oríire, sé bòbó yen náà ni?” Tósìn dáhùn pé “Béè ni sir”
“That’s good, sé’wo náà ti wá rí i pé èyìn onísùúrù l’Olóhun má a n wà?”
Inú Dérìn dùn láti gbó pé Tósin n múra láti se ìgbéyàwo.
Sé ni àsìkò tí Dérin sàkíèsí pé ara Tósìn ò yò níbi isé tó pè é láti bi í ní ohun tó selè tí inú rè ò fi dún ni Tósin sàlàyé fún pé òrò oko àfésóná òun ló n ba òun nínú jé, ó sàlàyé fún Dérìn pé kówèrè kówèrè ni àfésónà òun, bí i ti wèrè tó n sínwín kó ni Tósìn n so o, bíkòse tí àwon omoge onírúurú tí Akinadé tó jé àfésónà rè n kó kiri, èyí kò sì fí Tósìn lókàn balè nínú ìrìnàjò ìfé won, Dérìn gba Tósìn nímòràn láti sé sùúrù kó sì kún fún àdúrà gidigidi, Dérìn jé kó yé e pé òpòlopò okùnrin máa n fé jayé orí won nígbà tí wón wà lódòó kí wón sì pàsinmi pò léyin tí wón bà gbèyáwó sílé tan.
Títèlé ìmòràn Dérìn ló wá padà já s’ópé fún Tósìn, ìdì nìyí tó fi rò pé kó ye k’òun fún ògá òun ní káàdì ìpè náà níbi isé àfi kóun mú un wá sí ilé rè.
Bí Róláké sé sòkalè nínú okò ló ti róye pé oko òun nìkan kó ló wà nínú ilé, ó rò ó nínú rè pé Romólá ló níláti wà nínú ilé pèlú oko òun, sé Róláké kúkú ti fi ojú àti ìwà rè lé gbogbo òré lára oko rè.
Bó se dé enu ìlèkún ló gbó tí oko rè n bi eni tí wón jo wà nínú ilé pé “kín wá ní kí n fi se é lálejò báìí?” Róláké mi orí, ó réèrín ìyangì ó fi agídí sílèkùn ó wolé, bí Tósìn se rí ìyàwó ògá rè ó sáré dìde láti kí i dáadáa.
“E káàbò mà”
“Só ò wo wèrè? K’áwon ta ni káàbò?” ní ìdáhùn tí Róláké fún Tósìn.
“Rólá…”
“To bá p’orúko mi tí n bá ya bo èyin méjéèjì, àwon tí ò mò yín á ba yín káàánú” Tósìn n wo ìyàwó ògá rè tìyanutìyanu, ohun tó n selè ò gba ibìkankan yé e.
“ E má bínú mà” tí Tósìn so bí Róláké nínú, ó ju àpamówó rè sílè, ó sún mó Tósìn ó fún un ní ìfótí tó gbóná, Tósìn sáré sún séyìn ó di etí rè mú ó ni
“Hàhà!”kí Dérìn tó dìde Róláké ti sún mó Tósìn, ó tí ló aso mó on lórùn ó n wí pé “Tìe ti bá e lénìí, ayé e ti bàjé lénìí” Tósìn fí agídí já ara rè gbà, ó n sá a lo Róláké fé sáré tèlé e, Dérìn sáré dì í mú tí Tósìn fi sá jáde.
“Òjòwú, so tún fé má lé omo olómó lo ni?”
“Fi mi lè jòó, oníranù òsì” ó fi ìbínú já ara rè gbà, o n mín lókèlókè bí eni tó sèsè sá ere orí pápá tán.
“RÓLÁKÉ, so fé so pe o ò dá secretary mi mò mó ni?
“Nígbà yen wá n kó? Sé ilé ló ye ke tún gbé’ra yín wa? Gbogbo ìranù te ti se l’office ò to yín”
“ Róláké nítorí olóhun, wedding invitation omo ‘ìí ló mà mú wá fún mi”
“Ayé yín ti bàjé, Dérìn, léyìn tó ti lo gbogbo àlùbáríkà ara wèrè è tán, ó wá fé gbé kòrònfo lo fún eni eléni, wò ó, ó dùn mí pé mí ò mo oko è, èmi ni mi ò bá tú wedding yen ká kó tó dojó yen, olóríburúkú gbogbo” ó mú àpamówó rè nílé ó pòsé ó sì bínú wo yàrá lo.
* * * * *
Bí Àjoké se fi ìbínú kúrò lódò àwon òbí rè tààrà òdò Àsàbí ló m’órí lé, Àsàbí rí ójú òré rè tó kóré lówó ó sì bi í ní ohun tó dé, Àjoké kò fèsì ó fi owó se àpèjúwe fún Àsàbi, ó sì ti yé Àsàbí pé kò ní sòrò àfi tí wón bá dé abé igi tí wón tí má a n so òrò awo tí etí keta kò gbodò gbó.
Àsàbí pa ohun tó n se tí, wón sì kórí sí abé igi òsàn tó wà ní inú igbó tí kò jìnnà sí ilé àwon Àsàbí.
Wón jókòó lórí òkúta gégé bí ìse won, wón n wójú ara won, léyìn bí i ìséjú méta, Àsàbí sòrò ó ni “òré è mi, Àjoké è kó omo ajífojógbogbo dára bí egbin, emi ló dé?
Emi ló selé? N tó bá dé ni o so, òrò kán o ní tóbi títí ká fòbé bù ú, ìsòro tó bá sì débá ójú tìe ti dé bá imú tèmi, dákun ìmùlè mi, ohun tó bá dé ni kó o bùn mi gbó”
Àjoké mí kanlè, ó sì fi tomijétomijé sàlàyé òrò fún òré rè, enu ya Àsàbí láti gbó pé irú Àjoké ni Balógun wá fé fi saya, ní Balógun tó se pé ìyàwó méta ni n be lóòdé rè, àwon àti àkóbí ìyàwó keta rè jo parí ní ilé ìwé girama Alákúkò ni, Àsàbí rò ó nínú ara rè pé òdún mélòó gan ló kù fún Balógún láti lò láyé gan tó fí wá fé tí kékéré so òré òun di olóríburúkú.
Àsàbí bí Àjoké léèrè ohun tó fé se sí i, Àjóké fún un lésì pé òun ò mo ohun tí òun lè se lóun se tò ó wá.
“Àjoké, ònà àbáyo méjì ló wà fún o, yálà ko gbà á ní kádàrá re, kó o fé…”
“Fé ta ni? Kí n f’árúgbó kí n jogún pósí, ó doódì” Àjoké tàka òsì dànù
“Tàbí kó o sá kúò nílé”
“Kí n sá nílé? Hmmmmm”
Àjoké mí kanlè, ó ronú ló gbárí, sá nílé kè? Òun? T’óun bá wá sá nílé, báwo ni àwon òbi òun se fe mà a jeun? sebí òun náà lóun n sé púpò nínú àtije àtimu àwon, sé ebi ò wá ní lu ìyá àti bàbá òun pa báyìí? kò mo ìgbà tó sòrò síta pé,
“Sebí bòdá Sánjo wà fún won”
“Sanjó? Kín ni ti Sanjó nínú òrò tó wà nílè yìí? Àbí o fé fi tó Sanjó létí ni? Àsàbí bi Àjoké léèrè.
“Iró o, kín ni wón fé se sí i jú kí wón tún ta kò mí lo”
“Èmi ti mò télè pé ègbón re ò lé sanjó kankan, kódà kò dá mi lójú pé ìgbèyìn ègbón re le dáa”
“Hàhà! Àsàbi, ègbón mi ló mò n sépè fún un, kín la gbé kín lo jù? A gbá ni lójú ojúgun n sèjè, ta la gbá létí ta léti n ro? Sèbí èmi légbón mi se? N ò f’ègbón mi báàyàn seré o”
Ti imú kúkú yé‘mú tí fí n soje béè ti orùn y’órùn tó fi so gègè, tí Àsàbí kúkú yé e tó fí fí ogbón fi èpè ránnsé sí Sanjó.
Sebí olólùfé ìgbàkan Sanjó ni Àsàbí jé, ìjà ló dé lorin dòwe.
Sanjó se òpò ìlérí olósèlú fún Àsàbí nígbà tó n múra fásitì ìlú Nla, ó se ìlérí fún Àsàbi pé òun kò ni nífèé obìnrin kankan mó léyìn rè, èyí tó wá n dun Àsàbí jù nínú òrò náà ni tí ìbálé Àsàbí tí Sanjó fi enu dídùn òun ètàn gbà lówó rè lójó tó ku òla tí Sanjó n lo sí fáfitì ìlú Nlá.
Sanjó fi yé Àsàbí pé kó jé kí àwon bá ara won lásepò tó bá se pé lótìító ló nífèé òun dénú gégé bí o se so, Àsàbí kókó kò jálè súgbón nígbà tí Sanjó sàlàyé fún un pé ohun tí àwon bá jo ní papò fún ìgbà àkókó dúró gégé bí i ìmùlè láàrin àwon méjéèjì, èyí kò sì ní jé kí òun lè dà á tàbí ko enu ìfé sí obìnrin kankan mó títí láé, Sanjó wá fi kún un pé tí òun bá dà á tàbí bá obìnrin mìn-ín ní àjosepò kí ìbálé tí òun fé gbà lówó rè sèdájó fún òun, báyìí ní Àsàbí se gbà fún Sanjó láti bá a ní àjosepò tí Sanjó sì so ó di obìnrin.
Ìgbà àkókó tí Sanjó yóò padà wá sí ìlú Alákùko léyìn tó ló sí fásitì ló yí ìwà padà sí Àsàbí, ó sì fi yé Àsàbí pé egbé eye leye n wó tò, ó ní òun ò rò pé ìfé ààrin àwon lé wò mó, Àsàbí rán an léti ìlérí àti ìmùlè tó wà láàrin àwon, Sanjó so fún un pé erémodé àti òrò orí ahón lásán ni, pé àtipé gan lódò àwon ará oko bí i Àsàbí ni ìbálé ti jojú, kò jojú mó lójú àwon ará ìgboro bí i ìlú Nlá.
“Mó bínú, ara ló ta mí ju bó se ye lo, o mò pé o jìyà nítórí ègbón re ju kó wá jé p’óun ní o mo ta ko àtikàwé re lo” Àsàbí be Àjoké.
“Elénu rúnrùn ló làmù ìyá rè, èmi n mo lègbón mi, ègbón mi ló ni mi”
“Oooooo, a ti gbó o”
“Jé a padà sórí òrò t'á n bá bò, bí n bá wá gbà láti sá lo, ibó ni n o sá lo? Àtipé, Kín ní n mo se níbi n bá sá lo?
Àsàbí fi yé òré rè pé eran tí kò yí lòrò sísálo Ajoké kò sì wá òbe rárá, ó ní ìlú Ajé ló tóbí dáadáa fún ènìyàn làti sá lo, ó sàlàyé fún un pe òrò ajé sì wà ní ìlú Aje dáadáa.
“Báwo ni n se wa dé ìlú Ajé àtipé òdò ta ni n mo gbé nílùú Aje?”
“Èyun ò le, mó fe lo wo àbúrò bàbá mi nílùú Ajé lótunla, bí n bá dé ìlú Ajé, n ó wá Lálónpé kàn, n ò sì sàlàyé fún un, ó sì dá mi lójú pé yóò gbà láti gbà ó sódò fún'gbà díè”
Inú Àjoké dùn ó sì dì mó òré rè, ó kí i pé ó seun.
Àjoké pàdà sílé pèlú ìdùnnú, ó sì lo be bàbá rè kí wón má se bínú sí òun fún ìwà àfojúdi tí òun wù léèkan, ó wí pé àyà ló ka òun súgbón bí òun se fí òrò lo òré òun Àsàbí ló bá òun so èyí tí i se òótó òrò, òun sì ti gbá láti fé bàbá Balógun, inú àwon òbí rè dùn, wón se àdúrà fún lópòlopò, ìpalèmó èètò ìgbéyàwó sì bèrè ní pereu.
Àjoké àti Àsàbí ríra léyìn tí Àsàbí ti òdò àbúrò bàbá rè dé, ó sì fi tó o létí pé Lálónpé ti gbà láti gbà á sòdó, wón jókòó jíròòrò lórí ogbón tí won yóò dá.
Ìgbéyàwó n sún mo, ìpalèmó n lo ní repete, Balógun gbé òbítíbitì owó kalè fún ayeye ìgbéyàwó náà, Àjoké àti Àsàbí náà n ra orísìírísìí ohun ìlò àti èsó nínú owó tí baba rè fún un fún ti ayeye ìgbéyàwó tó n bò lónà, Àjoké fi èjè sínú ó sì n tu itó funfun jáde kí àwon ènìyàn má ba fura.
Ní ìdájí kùtùkùtù ojó ìgbéyàwó, kùrùkere ti bèrè ní ilé àwon ìyàwó àti okooyàwó, Àjoké lo bá bàbá rè láti wúre fún un, bàbá rè súre fún un lòpòlopò,ó sì bá a so òrò ìsítí orísirísi kí Àjoké tó lo bá ìyá rè àti àwon àbúrò bàbá rè ní ìyèwú, àwon náà súre repete fún un, wón sì bá a so òpòlopò òrò lórí bí ilé oko se rí. Àjoke bu omi láti lo wè, Àsàbí sì bi í léèrè pé sé kí òun telé e, Àjoké ní kí ó má sèyonu, àbúrò ìyá Àjoké tó wà níbè fèsì ó ní “Hówù Àsàbí, o ò se kúkú mó tèlé òré re relé oko” Àsàbí dáhùn pé “bó bá seése” gbogbo àwon tó wà níbè bú sérìn-ín, Àjoké sì gba balùwè tó wà ní àgbàlá ilé baba rè lo láti wè, sé ìwájú ilé kúkú ni àwon tí n sèètò jíje wà.
Àjoké wo balùwè yabuge náà, ó gbé omi kalè, ó bó aso tó ró mó àyà, ó ta á dí enu ònà bí wón tí má a n se, ó wo ègbé kan ó ri òrá dúdú tí Àsàbí ti wá fi ogbón fí síbè láti alé ìyàwó ku òla, sé ó ku ojó keta ní Àsàbí tí n sun ilé òré rè.
Àjoké sáré tú òrá, ó mú èwú tó wà níbè ó sáré wò ó, bí Àjoké se wo síkéètì tán tí o múra láti gbá ibi èyin páànù jáde ló gbó ìró esè, Àjoké kó ara ró, ó rora yojú ó sì rí i tí eni náà bèrè láti tò, Àjoké fí iké bú omi, ó sì dá a sílè bí pé ó n bu omi sára.
Nígbà tí eni n tò tò tan ó wí pé “Ìyàwò, e kúùwè o” ó sì kúrò níbè. Àjoké kò se méní se méjì, ó gba ibi tí páànù ti yanu sílè, ó sì f’esè fé e.
Àjoké n sáré àsáwèyìn títí tó fi dé’bi tó gbé àpò sakasaka tó di aso rè pamó sí, ó sí àpò lénu, ó sì mú jèlìbábà eléhàá kan jáde, ara rè kó tíò bó se di jèlìbábá náà mú.
Kì í kúkú se pé Àjoké dìídì lo rán jèlìbábá, lójó tó kiri epo dé ilé Ààfáà Kéwúdolà tí kò bá enikéni nílé ló tajú kán rí àwon aso eléhàá tí àwon omo kéwú fò sá, ní kété ni èrò kan ti so sí Àjoké lókàn, ó sún mó ibi tí àwon aso náà wà, ó bèrè bí eni fé tò t'òun ti igbá epo lórí, ó wò yán án yàn àn yán, ó sì fi ogbón ré jèlìbábà eléhàá Ààfáà Kéwúdolà, ó ká a sínú igbá epo rè, ó sì korí sí ònà ilé won.
Àjoké gbé jèlìbábá wò, ó gbé àpò aso nílè, ó sì mórí lé ònà ibùdókò.
Léyìn bí i wákàtí kan tí Àjoké ti wo balùwè lo, Àdúnní yojú wo ìyèwù tí ìyàwó àti àwon elégbé rè wà ó ní “séyàwó ti múra tán?” òkan dáhùn lára àwon elégbé ìyàwó ó ni “Ìyá wa, múra tán àbí kín n la? Ìyàwó tí ò tí kúrò ní balùwè, Jo n pé'yàwó fé we gbogbo èyí tí ò wè látèyìnwá dànù fún Bàbá Balógun ni” Gbogbo wón réèrín Àsàbí sì dáhùn pé “èyin le mò, e fi òré mi lè ò jàre.”
Àdùnní korí sí balùwè láti kan omo rè lójú, ó sún mó balùwè ó pe Àjoké, nígbà tí kò gbó ìdáhùn ó ye aso sí ègbé kan, ó ri omí àti igbáàwè Àjoké láì rí Àjoké, ó fi igbe ta “E gbà mi o! E gbà mi o!!
Aráalé e gbà mi o” Gbogbo ènìyàn ró jáde látí inú ilé àti àyíká, èèmò dé ìyàwó pòórá lójó ìgbéyàwó, Àwon ènìyàn bèrè sí ní wá Àjoké kiri gbogbo agbègbè àti àyíka, tó fi mó inú igbó àti inú àwon kànga.
Àdùnní n yíra mólè ó n sunkún béè ló n gbé ara rè sépè, Àsàbí bara jé ju Àdùnní lo, bó sé n sunkún béè ló n wí l'óhùn arò pé “tèmi mò bá mi o, ayé mi mò bàjé o, haà! Ìkúnlè abiamo o, e sì f'òré mi dá n lóró, èyin ayé, e è sì sàánú ojó ìkúnlè” bó bá sunkún díè, a janra rè mó'lè, a sáré dìde ràbàràbà láti má a sá lo, àwon èèyàn a sáré dì i mú pèlú òrò ìtùnú pé òré rè fé è dé. Ako igi ò gbodò soje, Àdìsá so orí kó, àwon alábàásàjoyo tó di olùbánikédùn rògbà yí i ká, wón n rò ó kò sokàn akin.
Òkìkí ti kàn ká gbogbo ilú, ìròyìn sì ti kàn délé Balógun, oníkálukú bèrè orísirísi òrò, àwon kan ní Àjoké ti rìn lo níhòhò, àwon kan tíle n so pé ìyàwó Balógun keta ló sà sí i, enìkan ní bóyá Àjoké sì sá lo ni, òpò ló denu bò ó pé Àjoké ìí serú omo béè.
Omo àbúrò ìyá Àjoké kan ló wo yàrá Àjoké láti bó aso ìmúròdé orùn rè sílè kí ó wá aso Àjoké kékeré kan wò, sèbí ayeye tí wón wá fún náà ló ti dì bó se dì un.
Bí Bósè sé n tù àpo aso Àjoké ló sàkíèsí pé gbogbo aso tó jé àwon aso gidi inú aso Àjoké ni kò sí níbè, ó sì pàkíèsí àwon èèyan sí i, wón pe ìyá àti bàbá Àjoké wolé láti ye àpótí aso Àjoké wò, wón sì rí i pé níse ni Àjoké gba balùwè sá lo.
Àdìsá fi ìbínú bó síta gbangba ó sì n gbé Àjoké sépè ní mésàn mèwàá. Àwon abákédùn n dúrò ni méjì méta, àwon kan n yín Àjoké fún ìgbésè akin tó gbé, àwon kán sì bu enu àté lu ìwà ìdójútini ti Àjoké wù sí àwon òbí rè.
Kò pé tí Àjoké dé ibùdókò tí okò fi kùn nítórí ojó yìí ni ojó ojà kan tó gbajúgbajà ní ilú Ajé, okò gbéra ó dí ilú Ajé, léyìn ìrìn wákàtì méjì, okò wo ìlú Ajé, Àjoké kò nílò láti bèèrè pé sé àwon ti wo ilú Ajé tó fi mò pé òun ti dé ìlú Ajé.
Bí okò Alákùko se wolé sí gárèjì ni Lálónpe n wo àwon ti wón n bó sílè nínú okò náà, kò rí eni tó jo Àjoké ó n wò yéleyèle ó n rò ó nínú ara rè pé “Àbí Àjoké ò tètè ráyè kúrò nílé tí okò fi sí ni? Àbí àkàrà tú sépo níbi tó tí n sá lo ni?” Bí Lálónpé sé n se ìbéèrè lókan ara rè ló wòye pé eléhàá tó sòkalè nínú okò n to òun bò, eléhàá náà sún mó Lálonpé, ó sì pe orúko rè, Lálónpé ti tètè dá ohùn òré rè mò wón sì dìmó ara won gbàgì. Léyìn tí wón kí ara won tán, Lálónpé dá òkadà dúró, ó dárúko ibi tí wón n lo fún olókadà, wón jo dúnàn-ándúrà, wón sì ta mó òkadà.
ÌGBÈYÌN n tèsíwájú...
© RASBAM
2018
Orísun: Rosheedat Bamidele Amusat
0 comments:
Post a Comment