- 5 -
Ojó n yí lu ojó, osù n yí lu osù, kèrèkèrè ó n pé odún keta lo tí Àjoké ti sá kúrò ní ìlú.
Gbogbo nnkan le kòkò fún Àdìsá àti aya rè, àtije àtimu di ogun, sebí Àjoké tó n se púpò nínú àtije àtimu won ló ti tìtorí àìfé fé Balógun sá kúrò nílùú yìí. Igi ló kù tí Àdìsá àti aya rè n sé tà, agbára káká ni wón sì fí n jeun èèkan lójúmó.
“Mo kúkù mò pé báyìí ko ni yóó mo rí lo, gbogbo rè n bò wá dèrò bó pé bó ya” Àdùnní so fún oko rè pèlú ìrètí nídìí ìsu tí wón n sun láti fi se oúnje àárò àjemósàn-án.
“Àmó, ìrètí pípé a mó sokàn láàárè, mó sebí odún kan péré ni àwon àgùnbánirò fí n sin ilè baba won ni? Bó o wá ni t'Omoníósanjó se wá jé? odún keta rèé, à ó r'ómira béè a ò ríbèékùn.”
“Béè ni o, baále mi, à à gbúròó won, omo ni omo ni, omo pa Oláafá, Oláafá kú tán omo n kan‘lé, a ò rí ago rè pè, sebí bí Àjok… Àdìsá kò jé kí ìyàwó rè sòrò jálé tó fi gé òrò mó on lénu ó ní, “ó tó báun, mó ti ní n ò fé gbó orúko olóríibú omo un nínú ilé ìí mó, omo jákujàku, omo òfò, omo àdánù tí ò ní dáa fún wo lo fé dárúko rè? omo kan soso ni mo bí, òun náà sì ni Omoníosanjó tí n bò wá sanjó fún wa, èmi kó ni mo ni àkúkúùbí omo pò bí òsan un” Àdùnní bú sékún bí oko rè sé n fi èpè ránnsé sí Àjoke, Àdùnní lérò pé ó ye kó ti tán nínú oko rè léyìn odún keta sùgbón nísé ni inú Àdìsá túbò n le sí i.
Lójú Àdùnní kò ye k'ábiamo tòótó bínú sí omo bíbí inú rè débi kó mó on fi garawa won èpè fún un.
“ O ò bá à sun èjè, b’ísu bá jinná o gbé bá mi níyèwù” Àdìsà bínú wolé bó ti sòrò tán, Àdùnní fi ohùn jééjé be Olóhun kí ó mó se jé kí gbogbo èpè oko rè se lórí Àjoké, ó be Olóhun kí o bá òun só o níbikíbi tó bá wà, kí òun sì fi ojú kan àwon omo òun méjéèjì láyò àti àlááfíà.
Ní ìròlé ojó kan, Àdùnní wà ní iwájú ilé won tó ti di yabuge tán, o n sé ègúsí, bó se n sé ègúsí ló n fi orin se àdúrà fúnra rè,
“Ori mi jé n jèrè omo,
Ori mi jé n jèrè omo,
Ta ni ò mò pésé omo po,
Orí mi jé n jèrè omo,
Ta ni ò mò pésé omo po,
Eledá mi jé n jèrè omo”
Kò sírí sókè títí ti Sanjó fi kàn án lára tí onítòhún fi kì i kúùròlé.
“E kú…” ó sírí sókè ójú òun àti omo rè se mérin, ó sáré gbé igbá ègúsí kúrò lórí esè, ó fi tayòtayò dìde láti yò mó Sanjó, bó se fé dì mó Sanjó ni Sanjó sáré sún séyìn.
“Màmá, e ní sùúrù ná”
“Hàhà! Omoníósanjó, emi ló dé, sé mo su ára ni? Àbí mò n rùn ni?”
Àdùnní n yera rè wò bó sé n bi omo rè léèré tìyanutìyanu.
“Please, don’t misquote me”
“Kóòtù, èwo lòrò ilé-ejó n’nú òrò tó wà nílè yìí? Só o báàyàn jà níbi o ti lo se àgùnbánirò n wón fi pè o léjó ni?”
Àdùnní bi Sanjó
“Oooooohhhh, so irritating! Mi ò sòrò nípa ilé-ejó or whatever…”
“Wón n ta ofà? Àwon wo ní n tafà, sé ‘on fé peye ni?”
“Oooooh” Sanjó fi àtélewó gbá orí léraléra.
“Wòó oko mi, f'èèbó lè ná, jé a wolé”
Sanjó wó ilé bàbá rè tí atégùn òjò ti da ègbé kan rè wó lulè tìkàtègbin, ó pòsé, ó ní, “níbo? E wò ó, ayé ti lajú kojá gbogbo life tè n lo nílùú yín o, mí o lè wo inú ilé àlàpà yìí o, mi ò lè jé kílé wó pa mi”
“Sanjó, lénu re? Ilé àlàpà? Só o gbàgbé pé‘nú ilé àlàpà yìí la ti tó o dàgbà ni?” Àdùnní fi yé omo rè, ó sì n fi owó gbá ara ilé bó sé n sòrò.
“Nígbà kan nìyen màmá, ó dàbí pé e è mò pé Sanjó ìgbà kan ti yàtò sí Sanjó tó dúró níwájú yín” Enu ya Àdùnní pélù rádaràda tí n jáde lénu omo rè, ó rí i pé owó ti jóná, ó rántí ojó oúnje èèkan lójúmó, ó rántí ojó t’áwon n sisé t'áwon ò ní lè jeun gidi sénu ara àwon nítorí Omoníósanjó, Omoníósanjó òun ló wá dé yìí o, Àdùnní mí kanlè, ó jókòó, ó fi owó lérán, ó n wo Sanjó tìyanutìyanu.
Àdìsá yo lókèèrè pèlú igi lórí, ó fi owó òsì rè gbá igi mú, ó mú àdá lówó òtún, ó n làágùn bòlò, Sanjó sáré gbé ojú lónà òdò bàbá re bó se rí i pé bàbá òun ló n bò.
ÀdÌsá ru erù dé òdò won, ó bèrè láti so igi kalè, “Akòwé, dákun ní n ló'ó” Sanjó se bí pé kò gbó, Àdùnní sáré dìde sí oko rè, wón so igi orí rè kalè, bí wón se so igi kalè tán, Àdìsá fi ara balè wojú akòwé tó dúró, ó sì ri pé Sanjó ni.
“Omoníósanjó, ìwo ló dúró ni mo n ru erù bò lò n wò mí bò bí i àgùtàn, èyin alákòwé mò go, aáyánga re láí” Àdìsá sí fìlà lórí ó fí n na Sanjó, Sanjó sún séyìn ó gbon ara rè nù ó ní, “Bàbá kín ló dé gan? Sé fé dòtí white mi ni?” Enu ya Àdìsá, ó tún Sanjó wò làtòkè délè, ó kojú sí ìyà Sanjó ó ní “Ìyá Sanjó, ò n wò mí níran ni? Gbà mí, àbí mo sììyàn mú ni? Sé Sanjó kó ni?”
“Hmmmmmm! Sanjó kúkú ni, bó se sèmi náà ní kàyéfì nùn ún” Àdùnní sàlàyé gbogbo bí Sanjó se dé àti gbogbo èsì tí n fún ìyá rè, Àdìsá kò gbàgbó, ó kojú sí omo rè ó sì bí i léèrè pé, “N gbó, Sanjó?”
“E wò ó, I don’t really have much time, mo kàn wá rí àwon àna mi ni”
“Ìwo ti ni àna ni? Ìgbà wo lo gbéyàwó tó ò jé a mò? Kò lè jé pé òdò àwon Àsàbí lo…”
“Tá ló ma fé onídòtí yen, e wò ó” ó kó egbèrún méjì àti èédégbèta náírà jáde lápò ó nà án sí won, “One one thousand naira fún èyin, five hundred naira fún Àjoké” àwón méjéèjì wo Sanjó, wón mirí.
“Mó sèyonú, fi owó re sówó” Àdìsá àti Àdùnní jo panupò wí i bí eni pé wón ti kóra won.
“Kò sí wàhálà, if you don’t collect it, beggars will, mo kàn wò ó pé kò ní dáa kí n wá sábúlé yín, kí n má yà wò yín ni” Bí Sanjó se sòrò tàn ni Sadé gba ara ilé won jáde, bí Sanjó se rí i, ó ni “sweetheart,” Sadé sún mó on ó sì fowó kó o lórùn, Sadé bí i léèrè idí tó fi pé tóun wá retí rè léyìn ìgbà tóun to èru sínú okò tán, Sanjó dá a lóhùn pé kò si.
“E pèlé sir, e rora mà” Sadé kí Àdùnní àti Àdìsá, won ò dáhùn, wón kàn n wò wón bí sinimó ni.
“Dear, let's go” Sanjó fi owó kó Sadé lórùn kúrò níbè, wón sì gba araalé Àdìsá lo. Bí wón se lo tán Àdìsá káwó mó'rí ó ní “págà! Nnkan se mi, méwàá se mi o” Àdìsá fìdí jálè ó n yíra mólè “Mo f'owó ra’kú o, ìyà je mí o, òfó se mí o” Àdùnní n fa oko rè dide Àdìsá túbò n yíra mólè, ó sì n wa ekún mu bí i omodé.
* * * * *
“Ròmólá, kín ló fé fa òsì oríburúkú yen fún e? ni ìbéèrè tí Bólà gbé ko Ròmólá bí wón se wolé láti ilé ìtajà kówópé tí wón ti lo ra àwon ohun èlò àtí àwon ohun ìpanu.
“Kín lo mean?” Ròmólá fi ìbéèrè dáhùn ìbéèrè pèsìje tí ìyàwó rè bèèrè.
“Má bi mí ní ohun tí mo mean jòó, ìwo oníranù òsì yìí”
“Bólá, sé èmi ní oníranù? Èmì?” Ròmòlá fi owó kan àyà bó sé n bèèrè lówó Bólá.
“Hún hùn, ìwo kó, èmi ni, o rò pé mí ò rí gbogbo rubbish tíwo àti girl tó gbe níwájú gbe léyìn yén sé ní supermarket léèkan” Òrò Bólá sésé wá yé Ròmólá ní, ó sèsè mo ìdí tí Bólá fí n kanra ní gbogbo ìgbà tí wón wà nínú oko, gbogbo bí Ròmólá sé n bà a sòrò níse ló fi gún lágídi, ìgbá tí Ròmólá rí ìsesí Bólá, ó yá a kójú mó okò tí n wà.
Bí wón sé jáde sí enú òná ilé ìtajà Kówópé ni Bólá rí i pé omobìnrin tó n wolé ìtajà bò tejú mó oko òun, èèkàn náà ni omobìnrin náà pe Rómólá “Ròmólá Agbábíàká” ìgbà tí Ròmólá gbó orúko rè ló tó gbé ojú sókè wo omobìnrin tó n bò, bí Ròmólá sé rí Tóyòsí ó pariwo “Tóyòsí Ayélàágbé” Àwon méjèèjì dìmó ara won gbàgì, inú bí Bólá, ó dà bí kó rí àdà kó fi bé Tóyòsí sí méjì, ó pòsé tí kò dún sókè, ó fi ìgbónára kúrò níwájú won, ó lo dúró sí ara okò oko rè lóòókán, ó sì n wo Tóyòsí tìkàtègbin.
Ròmólá àti Tóyòsí kíra wón kú ojó gbooro bí í owó aso, wón sì bèèrè àlàáfíà ara won, Tóyòsí sòrò ó ni “o ti di big man o” ó sì fowó pa Ròmólá lérèké, inú bí Bólá níbi tó dúró sí, ó pòsé, ó sì mi orí.
Tóyòsí béèré ìyàwó àtomo, Ròmólá nawó sí Bólá níbi tó dúró sí, Tóyòsí juwó sí Bólá lóòókán, Bólá se bí i pé kò rí i, ó sì fìbínú sílèkùn okò, ó jókòó síwájú okò.
Tóyòsí fi yé Ròmólá pé oko òun àti omo tí òun sèsè bí wà nílé, pé òúnje omo òun tó tán l’òun sáré wá rà, wón gba nómbà èro ìbánisòrò ara wón kí wón tó dágbére fún'ra won.
“Òrò e sèsè wá ye mi ni, so fún mi, kín ló n jó e lówó tó ò fi jo'lè? Èsè wo ló wà nínú kí n kí former school mate mi?”Ròmólá béèrè pèlú ìbínú.
“Kíkí lè n kíra yín lè n dìmó ara yín lójú mí? Ti aparun wo gown yen náà n f'owó gbé e léèké jó àbí?”
“Sé èsè wà nínú bí mo se dì mó on? Bólá, kín ló dé tò n se báìí? Sèbí ìwo náà lo school?”
“Fine, ó wá di èmelòó témi rí school mate mi tó j’ókùnrin tí mò n dì mó? Ìwo nìkan ni, àfi bí àfise, bí ò jé old friend, ó ma jé ex girlfriend, séwo nìkan ni?
Wò ó, gbogbo nnkan ni mó le fi báàyàn seré o, bí i t'oko mi kó o, mí ò le sorogún láéláé, ìyen d'àyé àtúnwá, ko jé kí orí e pé” ó pòsé, ó sì fìbínú wo yàrá lo, Ròmólá jókòó, ó doríkodo ó n bi ara rè léèrè pé, Sé ègún ni ká pe eléyìí ni? Àbí ogun? Àbí kò má lo jé pé èsan àwon ìwà tí ìyá àwon wù sí bàbá àwon ló n ke lára àwon omo méjéèjì.
Ròmólá fi ojú inú wò ó, ó sì ri pé gbogbo ìwà tí àwon ìyàwó àwon méjéèjì n wù kò yàtò sí ìwà tí ìyá àwon fi dá àrun èjè rúru sí bàbá àwon lára, Ròmólá wá fi òkan sé àdúrà kí òrò òun àti ègbón òun má padè já síbi tí òro bàbá won já sí.
* * * * *
Àjoké bèrè ìgbésí ayé òtun ní ìlú Ajé, Sé bí ó se dé ni Lálónpé ti sàlàyé ònà tí àwon omo tálákà bí i ti won fí n r'ówó, bí i kí wón se omoòdò olóúnje, se alágbàtà ojà, kiri omi tútù pèlú àwon nnkan ìpanu ní àwon ibùdókò.
Àjoké ti lo odun méta gbáko láì rí owó kankan tù jo nílùú Ajé, ó ti dán gbogbo rè wò, ó kiri omi tútù láìmoye ìgbà káàkiri àwon ibùdókò, èrè tó bá rí lórí rè, oúnje náà ni gbogbo rè n bá lo, ó se omoòdò nílé oúnje àjepónnulá níbi tí abó àfòkúdórógbó ti ba gbogbo owó rè jé tán lórí owó òòdúnrun náírà tí kò ni yo oúnje rárá, owó ara won ní wón fí n ra oúnje je lódò ògá won.
Àjoké ronú pé ìgbà wo gan l’òun tó fé r’ówó tù jo láti fi rán ara òun níwèé.
Lálónpé se àkíyèsí pé Àjoké ti n kó ìrèwèsi okàn, ó sì pinnu láti bá a wá isé omoòdò sí ilé àwon tí olóhun ké, tí àwon ò ráyè à n sisé ilé, irú isé yìí ni owó lórí ju gbogbo isé tí àwon n se lo nítorí pé ààyè oúnje òfé n be níbè béè sì ni bí ebi bá ti kúrò nínú ìsé, ìsé bù se, yàtò sí ti oúnje òfé, àwon owó péépèèpé kan a mó on yo, eyì tó bà sì tún lórí ògá gidi nínú àwon omoòdò lè ti ara ògá rè se oríire.
Bí Lálonpé sé n ti ibi tí ògá rè rán an bò lójó kan ló rí i àkíyèsí tó wà lára ilé rìngìndìn kan pé wón nílò omooòdò obìnrin, Lálónpé fi esè kan yá ilé láti fi tó Àjoké létí, sé Àjoké kò kúkú lo sí ibi isé láti bi ojó méta séyìn, ó ni o re òun, Lálónpé sì mò dájú pé rírè tó re Àjoké kìí se ti ibà, bí kò se tí isé àsekúdórógbó tí kò tún ní owo gidi lórí.
Àjoké àti Lálónpé gbéra, ó di ilé olóyè Ajísafé, wón gbá géètì bí won se dé iwájú ilé, Akilápá yojú wo àwon tó gbá géètì kó tó sí géètì fún won, ó jáde sí won ó sì bèèrè ohun tí wón n wá, Lálónpé so fún un pé àwon rí àkolé tí wón gbé sí ìta pè wón n wa omoòdò.
Akilápá dáhùn ó ní “Enìkan náà là n wá” Lálónpé fún lésì pé enìkan náà ló n wá isé, Akilápá ní kí eni tí n wásé nínú won wolé kí òun mú un lo sí òdo ògá òun, Lálónpé dágbére fún òré rè, Akilápá sì mú Àjoké to ìyàwó ògá rè lo.
Polen, ìyàwó Ajísafé kékeré fi òrò wá Àjoké lénu wò, ìdáhùn àti ìrísí Àjoké té e lórùn ó sì ní kí Àjoké wá bèrè isé ní ojó kejì, ó sì fi kún un pé kó kó erù rè lówó nítorí ilé àwon ni yóò mó on gbé, báyìí ni Àjoké di èrò ilé Ajísafé.
Àjoké rí i pé lóòótó ni òkan san ju òkan lo, ìgbádùn àti fàájì ni isé omoòdò ní ilé olówó, egbèrún méwàá ni lósù, oúnje òfé sì n pé ní èèmeta lójúmo, kò sì sí isé àsekúdórógbó kan, léyìn kó dáná oúnje, se isé ilé, fo aso ògá rè, kó sì lo sí ojà lo ra àwon ohun èlò, kí ògá rè sì tún rán nísè.
Àjoké náà tí n dán láwò, ó sì tí n rí owó fi pamó, léyìn bí i osù méta tí Àjoké dé òdò ògá rè, ó toro ààyé lówó ògá rè láti mó on lo fún ìdánilékòó kòmpútà láàrin aago méwàá òwúrò sí aago méjìlá òsán, Polen ní kò sí ìyonu níwòn ìgbà tí kò bá ti ni pa isé rè lára.
Àjoké kó èkó ìmò èro kòmpútà fún osù meta, ó sì gba ìwé èri rè sówó. Àjoké n bá isé rè lo nínú ilé Ajísafé láì sí wàhàlà kankan àfi tí Akilápá tó má a n fé bá a se àwon ere ako sùgbón ní ojó tí Akilápá rìn in níkàké látèyìn níbi tó tí n foso ni Àjoké fi ìbínú kìlò fún kí o mà bá òun se irú erékéré béè mó
“ E wò o, láyéláyé yin té bá tún bá mi se eré rádaràda yen, mà a fi ejó yín sun mummy, kín ló fé fa gbogbo òsì yen fún yín? E má jé kí n wojú yín o”
“Kín ló tiè má n sèwo omo i ná? Ako re tiè ti pò jù, kín lò n gbé tò n gbin gan? Ó dìgbà tí olúwa mí bá dé lósú to n bò ko tó mò pé ako ò ran inú ilé wa yìí”
“Bí olúwa yín bá dé, wón káàbò, sé kà wá má a sá lo ni? E kóranù kúrò lódò mi jàre, èyin àgbààyà òsì yìí” Àjoké pòsé mó Akilápá, ó sì kojú mó aso tí n fò, Akilápá hora kúrò lódò rè. Bí Àjoké sé n foso ló n ronú sí ohun tó fé selè bí daddy tí Akilápá n so bá ti ilú òyìnbó dé lósú tó n bò, sé daddy yóò lé òun kúrò nílé ni? Àbí daddy yóò ní kí òun má se tòun, níwòn ìgbà tóun bá tí n se isé òun bí i isé, tí òun ò sì kojá ààyè òun, kín ló fé mu òun kolu daddy tí i se oko ògá òun?
Oko ògá Àjoké dé ní osù tó tèlé e gégé bí Akilápá se so, Àjokè kò sì rí ìwà kankan tó sàjòjì nínú ìwa oko ògá rè, kò burú rárá, aláwàdà sì ni pèlu, bi ìyàwó rè sì se fi Àjoké hàn án gégé bí omoòdò tí òun gbà, pèlú oyàyà ló fi kí Àjoké tó sì gbà á nímòràn láti túbò tera mó dáadáa tó n se kí òun lè rí i gégé bí i omo rere tí ìyàwo òun pè é.
Ní òwúrò ojo Ajé kan, Polen ti gba enu isé tirè lo léyìn tó ti lo òsè kan nílé láti fi ara pá oko rè tó sèsè ti ilú òyìnbó dé, Àjoké ti tún gbogbo yàrá tó kù se, àfi yàrá oko ògá rè tó má a n tún se léyín ti oko ògá rè bá ti jáde wá sí yàrá ìgbàlejò láti wá wo amóhùnmáwòran gégé bí ìse rè látìgbà tó ti dé, Àjoké kànlèkún yàrá oko ògá rè láìmoye ìgbà, nígbà tí kò gbó ìdáhùn, ó wolé láti tún yàrà nàá se, Ajísafé wo balùwè tó wà nínú yàrà rè láti wè ló gbo tí enìkan n kànlèkùn, ó sì ti mò pé Àjoké, omoòdò àwon ni, ó rò ó nínú rè pé “owó ba omo ìí lónìí” kò dáhùn, nítorí pé o mò pé bí òun bá dáhùn Àjoké yóò pàda láti wá tún yàrá òun se nígbà tí òun bá jáde lo ni, ó lekeke mó ibe, bó se gbó ìró pé Àjoké ti bèrè yàrà òun ní títúnse ló rora yó kélékélé jádé, ó rí Àjoké níbi tó bèrè sí tó tí n nu tàbìlì kékeré egbè ibùsùn yàrà rè, ó rora yó kélékélé dé èyìn Àjoké, ó sì rá a mú látèyìn, ó wó o móra, Àjoké pariwo, “yéè!”
“Fi ara e balè”
“Háà! Daddy, e fimílè”
“Mà á fún e lówó”
“E yà jòó” Àjoké fi ìbínú sòrò, ó gbìyànjú láti já ara rè gbà sùgbón agbára Ajísafé jú tiè lo, ó tiraka yí ojú sí Ajísafé, ó sì fun ní ìfótí gbígbóná kan, Ajísafé sárè fi sílè, ó fi owó ra etí.
“You dare slapped me?” Ajísafé ranjú bèèrè.
“E jòó sir, tiyín ò ní bàjé, e kúrò lónà kí n jáde”
“Léyìn ìgbátí alátarodo, ó rò pé mà á jé ko jáde lófèé, IMPOSSIBLE” Àjoké fé fi agídí sá jáde, Àjísafé gbá a ní orùn mú, ó fi agídí tì í lu etí ìbùsùn rè, ó sùn lé Àjoké lórí ó sì n gbìyànjú àti fi tipátipá bá Àjoké se àsepò, Àjoké n jà fitafita ní abé rè, ó sì n bèbè tekúntekún pé “e sàánù mi daddy, e è ni se oríibú, mi o se’rú è rí” Ajísafé dáhùn ó ní, “iyen gan ló ma jé ko gbádùn è” Àjoké rí i pé èbè àti ekùn ò lè ran òrò tó wà nílè yìí mó nítorí ojú Ajísafé ti ran‘kó ni Àjoké bá figbe ta ó n pariwo “E gbà mi o, e gbà mi o, Akilápááá, Akílápááá…” Ajísafé fi owó bò ó lénú, Àjoké rántí ìgò otí tó fi sí ègbé ìbùsùn láti mú un jáde bí ó bá tún yàrá se tán, ó mú owó òtún lo sí ònà ibi tí ìgò wà, owó rè te ìgò, ó sì fi agídí fó oko ogá rè ní ìgò lórí, òòyì kó Ajísafé pèlú òjijì tí ìgò bá a, ó sì ré lúlè sí ilèélè,ó dákú lo rangbondan, èjè bò ó lórí, Àjoké sáré dìde, ó sá jáde láìpé òun pèlú Akilápá sáré wolé, Akilápá rí ògá rè nílè tòun tèjè lórí ó sáré sún mó ògá rè, ó gbé orí rè sókè.
“Àjoké, kín lo se fún won?” ó rí èkúfò ìgò ní gbogbo orí ìbùsùn, ó sáré ti owó bo àpò, ó mú èro ìbánisòrò jáde, o pe ìyàwó ògá rè “Hello, e tètè ma bò o, Àjoké ti pa daddy o”
“yéè, mo ti dáràn, tèmi ti bá mi, mo ti pààyàn” Àjoké bú sékún, o káwó lórí, ó n gbòn.
“Àjoké pa daddy kè?” ni ìbéèrè ti Polen n bi ara rè bó se n wa okò ni àwàsárá ló sí ilé bó se gba ìpe asógéètì won tan, kò wulè rónú lórí ohun tó le mú Àjoké pa oko òun, ó ti mo irú èdá tí oko rè jé, kò lé rí obìnrin kó má fé kojá lára rè, àfi bí àfise, òko rè kì í jé kí omoòdò pé nínú ilé wón, gbogbo omoòdò tí wón bá gbà ló má a n bá ní àjosepò, omoòdò kerin rèé láàrin odún méjì, omoòdò àkókó tí wón gbà ní bí i odún méjì séyìn sá lo fúnra rè láì lo osù méji nígbà tí oko ògá rè so ó di ìlù tó fé lù ú ní àlùfàya, níse ni elékeji lóyún fún oko ògá rè ní tirè, Polen kò se méni se méjì, ó mú un lo sílé ìwòsàn, ó bá a yo oyún dànù ó sì fún ni egbèrún lónà ogójì náírà, owo gbà má bínú pé kó má a bá tiè lo, kò jé kó padà sí ilé won bí won se kúrò ní ilé ìwòsàn, Polen ká omoòdò rè keta tòun toko rè ní kété to padà láti wá mú ohun tó gbàgbé sílè, ojú èsè ni Polen ti da erù rè síta, kò fi mo lórí àwon omoòdò nìkan, àlè tí oko rè ní síta kò lónkà, àfi bi àfise.
“Sé ká tiè ni oko mi try láti rape Àjoke, sé pípa ló wà ye kó pa oko mi ni?”
Polen wa okò dúró ní enu géètì, ó sàrè sòkalè ó sì sáré wolé lo, Polen sílèkùn yàrá oko rè wìrìwìrì, ó ri oko rè pèlú èjè, ó sáré sí oko rè, ó gbé orí lé e láyà, ó ri pé o n mí, ó dìde ó kojú sí Àjoké ó ní, “kín loko mi se fún e to fi fé pa á?” Àjoke n gbon, ó kílòlò dá ògá rè lóhùn “won won won fe rape rape…” Polen jágbe mó on “orí e ti dàrú, nítorí e lo se fé so mí d’opó òsán gangan àbi? O yá, hospital.” Akilápá àti Polen n gbé Ajísafé dìde, Àjoké fé sún mó won láti fi owó kún un, Polen jágbe mó on “K’óríburúkú kúrò lónà fún wa, omo àlè, kò i tí ì rape e tó ti fìgo da opolo è rú, bó bá wá rape e tán n kó o, wà á sá a wéléwélé bí i eran iléyá àbí?
Olóríburúkú” Polen àti Akilápá jo gbé e dé ìdí oko ní enu géètì, wón té e sí èyin, Polen sáré wonú okò ó di ilé ìwòsàn tó wà ní tòsí ilé won, Akilápá padà sí inú ilé ó sì bá Àjoké tó wararo sí yàrá ìgbàlejò, Akilápá bú sérìn-ín kèékèékèè, ó fi orin sénú ó sì n jó yípo Àjoké.
“yokolú yokolú, kò a tán bí?
Yokolú yokolú,kò a tán bí?
Ìyàwó gbóko sánlè, oko yoké
Yokolú yokolú, kò a tán bí?” Akilápá dáké orin ó ní, “ó tán àbí ò tán?
Asòròse làwa, àwa ìí sòrò dànù, mo ní gbogbo ako tó n se ò dènú ilé yìí, àmó sá Àjoké, o dájú o, nítorí pé olúwa mi fé yè ó wò lásán lo ba ti won jé báun”
“Sé won ò sá ní kú?” Àjoké béèrè pèlú ìpayà
“Ó n pé, bí olúwa mi bá kú, ohun tólúwa mi mò ón je ló polúwa mi”
Wón dé ilé ìwòsàn kí Ajísafé tó yajú sáyé, Wón fún un ni gbogbo ìtójú tó ye, bí ara Ajiísafé se padà bó sípò ló so fún ìyàwó rè pé òun ò fé ri omo rádaràda yen nínú ilé òun mó, bí wón se délé láti ilé ìwòsàn, Polen pe Àjoké, o kó owó isé rè ti osù tí wón wà fún un, ó ni kí Àjoké wolé kó gbogbo erù kó má a lo, Àjoké gba owó, ó dìde wo yàra lo, ó dúpé lówó Olóhun tí kò jé kóun lókùú èèyàn lórùn, ó palè gbogbo erù rè mó tomijé lójú, ó sì mú orí lé ònà ilé Lálónpé...
ÌGBÈYÌN n tèsíwájú...
© RASBAM
2018
0 comments:
Post a Comment