Ọrùn wọ ipínlẹ̀ Kano lánàá, 3/03/2018, nígbà ti àwọn alágbára, alẹnulọrọ olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà sọkalẹ si ipínlẹ̀ náà pelu bàálù orísìírísìí eléyìí tí Aare Muhammadu Buhari kò gbeyin nibẹ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí ṣẹlẹ̀ látàrí ìgbéyàwó ọmọ gómìnà ipínlẹ̀ Kano àti ìpínlè Ọ̀yọ́, Fateema Ganduje àti Abolaji Ajimobi.
Yàtò sì àwọn olóṣèlú, àwọn ọba aláyè àti orísìírísìí àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn láwùjọ pejupesẹ síbi ayẹyẹ náà. Kódà, Oba Lamidi Adeyemi lọ pẹ̀lú gbogbo igbimo Oyomesi láti bù ọlá fún gómìnà Ajimobi ẹni tí wọn tún pe ni Kosẹlẹri.
Omilẹgbẹ èrò lójú pópó ipínlẹ̀ Kano bí èrò hadji Saudi. Àwọn òṣìṣẹ́ alaabo dúró wamuwamu káàkiri origun mẹ́rin ipínlẹ̀ náà. Bí wọn ṣe ń yẹ inú afẹ́fẹ́ wo ni wọn fi èrò ìgbàlódé arinurode wo ohun tí awon eniyan gbé sábẹ́ aṣọ.
Àwọn olóṣèlú tí wọn ti rí ara wọn tọ́jọ́ mẹta ń yọ mọ ara wọn, wọn sọ̀rọ̀ wujewuje sì ara wọn létí, won a tú bù serin, bákan náà ni wọn tún di mo ara won gbagigbagi bí ìgbà ọrẹ méjì àtijọ́ pàdé. Ẹ̀gàn ni hẹ̀, "sugar ja" nílùú Kano
Fún ipolowo àti ikede
08032394964
yemoford@gmail.com
0 comments:
Post a Comment