Smiley face

"Ẹ má gbàgbé ohun tí mo sọ": Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n JJ Okocha

JJ Okocha ẹni tí wọn fún ni Muhammet Yavuz gẹ́gẹ́ bí orúkọ tuntun ni ilu Turkey nígbà tí wọn fún un ní iwe àṣẹ láti jẹ ọmọ ìlú náà ni kókó ọ̀rọ̀ wá fún tòní.

Yàtò sì wí pé ọmọ ìlú Enugu náà jẹ pidánpidán orí ọdan , ó jẹ́ olokoowo ńlá tí kìí pariwo, bákan náà ni òye ye pupọ nípa igbe ayé ẹ̀dá.

Ẹ jẹ ka wo ohun tí JJ Okocha sọ lẹ́yìn ọdún die to feyinti. Ní àkókò tí a ń wí yìí, àwọn ọ̀dọ́ lọ ń bá sọ̀rọ̀.

"Ẹ wá àgbàrá láti mú àlá yín ṣẹ".

Mi ò gbàgbé ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé àwùjọ wá ti sọ ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àìmọye àwọn  alàgbàra ni wọn si ti dabi ọlẹ.

Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì fún oníkálukú láti wá àgbàrá láti mu àlá wọn ṣẹ.

Àwọn àkókò kan wà tí yoo dabi wí pé ó fẹ́ sú yin, nítorí wí pé ẹ ti gbìyànjú gbogbo ọgbọ́n tí ẹ mọ.

Ẹyin nìkan kò lè wá ní ru òpó yìí. Púpò àwọn ènìyàn tó wà lókè ni wọn ni àìmọye ìrírí to jọ tí yín.

Iyato kan tó wà ní wí pé, wọn wá àgbàrá láti tesiwaju. Ẹyin ẹ fi fóònù yín ṣe àrìkọ́gbọ́n.

Bí ó bá ti kú, kosi ohun tó lè ṣe. Ṣùgbọ́n kété tí a bá ti tí í bọná to gba agbára ni yóò tún padà ṣenu iṣẹ.

E má jẹ ki ibanujẹ ọkàn sọ yín di alailagbara láti tesiwaju. Èrò nipa ijakule àná a má sọ ènìyàn di alailagbara.

Ẹ má jẹ ki ẹrú bayin ju láti gbìyànjú ohun tuntun. Ẹ ẹ̀ ri mo sọ wí pé kí ẹ má jẹ ki ẹrú bá yín ju, kosi ẹni tí kì bẹru ṣùgbọ́n ẹ má jẹ kò gbà gbogbo ọkàn yin. Àṣìṣe kii se ijakule, ọgbọ́n tuntun lọ ń kọni.

Tí ẹ bá ṣe àṣìṣe, ẹ dìde kí ẹ tún wà ọgbọ́n míì dá. Ẹ wá òye nípa ohun tó ru yín lójú. Àìní òye a má sọ ènìyàn di alailagbara. Ẹ bá onire yọ tinútinú, Ọlọ́run ọba tó rokan yóò fi ire san padà fún yín. Ẹ tẹra mo àdúrà, èmi ò rí ohun tí àdúrà seti. Ẹ má lára ẹni tó ti kọjá yín, ẹ má fẹnu bá wọn jẹ, kádàrá ó dọ́gba. Èdùmàrè lo mọ bo se n pín. Kosi gbàgbé ẹnikẹ́ni.

"E má gbàgbé ohun tí mo sọ, ẹ wá agbára láti mú àlá yín ṣẹ"- Augustine Azuka Okocha

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment