Smiley face

Ohun tí ẹ kò mọ nípa Ayodeji Ibrahim Balogun (Wizkid)

Ohun tí ẹ kò mọ nípa Ayodeji Ibrahim Balogun (Wizkid)
láti ọwọ́ Olayemi Olatilewa (Olayemi Oniroyin)

Ọdún1990 ni wọn bí si ìdílé musulumi ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́ ni ìyá rẹ. Wizkid sì feran láti má tẹ́lẹ̀ ìyá rẹ lọ sílè ìjọsìn.

Kódà ibẹ lọ tí bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ pẹlu àwọn ẹgbẹ́ akọrin. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, Wizkid ni ìṣòro pelu bàbà rẹ nípa orúkọ tuntun tí ń jẹ.

"Gbogbo ìgbà ni bàbá mi má n bá mi ja wí pé ibo ni mo ti rí orúkọ tí mo ń jẹ. Kò feran orúkọ náà rárá. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tí mo fẹ́ ṣe, àwọn ènìyàn tí mọ mi sì Wizkid.

Ìyàwó mẹta ni bàbá mi fẹ́, musulumi òdodo sì ni. Mo gbìyànjú láti ṣe àlàyé fún bàbá mi nípa oríṣi orin tí mo ń ko àti ìdí pàtàkì isafihan ara mi eléyìí tí orúkọ tí mo ń jẹ ṣe kókó nibẹ.

Gbogbo alaye mi dabi ìgbà tí ènìyàn yíngbàdo sẹ́yìn ìgbà ni. Mama mi ń ṣeju sì mi wí pé kí n má bá bàbà mi lo agídí àti wí pé kí n ní sùúrù pẹ̀lú rẹ. Bàbá mi sọ ohun tó fẹ́ sọ lọjọ náà, nígbà tó ṣe tán, mo dọbalẹ mo sì bá tèmi lọ. Inú mi ò dùn, ọkàn mi bajẹ gidi gan-an.

Ṣùgbọ́n mo mọ̀ wí pé tí "tẹ́tẹ́" mi bá jẹ, bàbà mi ma padà dọ̀rẹ́ mi. Nǹkan bí oṣù díẹ̀ sì ìgbà náà, àkókò yìí jẹ́ ọdún 2010, ní òkìkí tí a n sọ yìí bá dé. Mo lọ sí orile-ede Ethiopia lọ ṣeré. Mo gbà ibẹ wọ Nairobi to wá ni Kenya. Mo ṣeré fún ọjọ́ méjì ni Kenya.

Mo kúrò nibẹ wo South Africa. Mo ṣeré ni Johannesburg, àwọn ènìyàn yà wa wòran mi bí ẹni wí pé ayé fẹ́ parẹ́.

Bí mo ṣe ń ṣeré ni Southy ni wọn sọ fún mi wí pé won tí ra  tickets mi tán ni Zimbabwe. Igba ti mo parí iyide orin mi tán, mo padà wá sí Lasgidi.

Ọjọ ìsinmi to tẹ́lẹ̀, Mo gbìyànjú láti yọjú sì àwọn òbí mi. Bí mo ṣe sọkalẹ nínú mọ́tò pẹ̀lú àwọn isọmọgbe mi ní bàbà mi n pariwo 'Wizzy Wizzy Wizzy Wizzy my boy'. Orúkọ tí bàbá mi in bá mi jà lè lórí lọ padà sọ dórín.

A sé gbogbo bi mo ṣe ń lọ káàkiri ní bàbà mi ń wò mí lori TV 📺 . Gbogbo iroyin to ń ṣẹlẹ̀ simi lọ ń rí ká pátá. Inú mi dùn, mi ò sì lè gbàgbé ọjọ́ naa rárá". - Wizkid

Kí ni ẹ̀kọ́ tí eléyìí kó wá?

Ọpọlọpọ ènìyàn tí wọn kò bèrè rẹ lónìí ń bọ wá di ọrẹ rẹ to bá lu àlùyọ. Má banujẹ wí pé wọn kò ka ọ kún tàbí pọn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè.

Ohun tí ó ni láti ṣe ni lati sapá, gbìyànjú, tiraka, làkàkà láti jẹ èèyàn láyé.

To ba ṣubú nígbà mẹ́wàá, dìde dúró nígbà mewaa. Má rọ ara rẹ pín nígbà tí èmi rẹ bá sì wà.

Ma banujẹ nítorí àwọn kan pẹ̀gàn rẹ wí pé ò lọmọ, aya, ọkọ, iṣẹ, owó, ìwòsàn tàbí àṣeyọrí. Èdùmàrè ń bọ wá so ẹ̀gàn rẹ dògọ.

Jẹ akíkanjú, ní igbagbagbo nínú Ọlọ́run rẹ, ara rẹ, ẹ̀bùn àti ọjọ́ ọ̀la rẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá kò ní ìtumò pàtàkì, tí igbe ayé rẹ bá yí padà, ìtàn rẹ yóò yìí padà pẹ̀lú. Lai pé àwọn ènìyàn yóò sọ orúkọ rẹ dórín.

Fi ìgbàgbọ́ gbé e!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment