Smiley face

Yorùbá Ni Tòótọ́: Yorùbá kò ní pẹ tán tí a kò bá mọ nípa ìtàn wa

Mensa Otabil, olùkọ́ni , onkọ̀wé , olokoowo ńlá, àti ẹni àkọ́kọ́ ti yóò ṣe idasilẹ Yunifásítì aladani ni orileede Ghana sọ wí pé, "àwọn onímọ̀ sayẹnsi kì í sẹ̀dá ìmọ̀ wọn má ń ṣe àwárí rẹ ni" .

Mí ó lè kó ọ̀rọ̀ ọkùnrin ọmọ ìlú Ghana yìí dànù, nítorí ó wà lára àwọn ènìyàn tó lóye tí ilé Áfíríkà feyinti.

Tí Otabil bá sọ̀rọ̀ wákàtí kan, mílíọ̀nù ni wọn ọn san fún un gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ nítorí ẹ̀dá tí imọ rẹ fẹ́, ti arojinlẹ rẹ sì ba ni lẹ́rù jọjọ ni.

E jẹ ki tún sún síwájú diẹ sì i. Buckinghamshire ni ilu England ni wọn bí Terry Pratchett si. Onkowe to pedegé ni, àwọn alakada kì í sì fi ìṣe rẹ ṣeré rárá. Ẹ gbọ ohun tí ọkùnrin náà sọ:

"Ó ṣe pàtàkì kí a mọ ibi tí a ti mbo. Nítorí tí a kò bá mọ ibi tí a ti ń bọ, a kọ lè mọ ibi tí a dé dúró. Tí a kò bá sì mọ ibi taa de dúró, a kò lè mọ ibi tí a ń lò. Tí òye ibi tí a ń lò kò bá yẹ wá, ó dájú wí pé a ó sina dandan ni".

Ó ṣe ní láàánú wí pé àìmọye ọgbọ́n isembaye ni a ti sọnù nítorí wí pé a kò mọ ìtàn wá, a kò mọ ẹni taa jẹ.

Àìmọye ìmò ni yóò nira fún wa láti lẹ́bá nítorí wí pé a kò ṣe àwárí èyí ti àwa gan-angan ni. Imọ má ń bímọ imo ni. Tí a bá ní ọkàn yóò di méjì, tí a bá ní méjì ni yóò di mẹ́rin. Ènìyàn tí kò ní ohunkóhun ní kó ṣe dáadáa.

Mi ò ni so ohunkóhun lónìí nípa ìwé Yorùbá Ni Tòótọ́ láti owó Kunle Babarinde, ṣùgbọ́n, bóyá lóla, mo lè yí ọkàn mi padà. 

Ohùn tó dá mi loju ni wí pé, tí bá ka ìwé yìí tí a kò sì gbádùn rẹ dọ́ba. Èmi náà má ṣe bí ọba toni òun ò bá Yorùbá ṣe mọ. Má lọ sí òkè oya, má sì lọ má gbé láàárín awon Hausa. Mí ò ní jẹ Olayemi Oniroyin mọ, má yí orúkọ mi padà si Danladi Mai Labaran.  😂 


Ẹ kú ikale

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment