Àsegbé kan kò sì láyé, àsepamọ́ ló wà. Ọkùnrin tí orúkọ n jẹ Ifedioranma Darlington tí ń sisẹ́ adari ọkọ̀ ojú pópónà ni ìkòríta Aroma nílùú Awka, olú ipínlẹ̀ Anambra tí kẹ́san ìṣe ọwọ rẹ pẹ̀lú bí àwọn kan se dana ayẹyẹ ojo ibi fún un.
Tonílé tàlejọ̀ ni wọn mọ Darlington ni ìkòríta yìí. Bí òjò ń ro, bí ọ̀rùn un rán, èmi kan ṣoṣo ni fi i sìn ìjọba. Kí i gba rìbá, sọwọ́kuduru, ẹ̀gúnjẹ, owó ẹ̀yín, tàbí saa-ba-n-mu.
Àwọn kan ni wọn lọ ṣe ìwádìí ọjọ́ ìbí rẹ lọ́wọ́ àwọn ọrẹ, eléyìí tí ń ṣe ọjọ́ Jimoh to kọjá yìí, 18/05/18.
Awon ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi ọgbọ́n gbé lọ síbi tí fàájì tí ń dúró de e, ẹnu yà maanu yìí nígbà tó rí àwọn ènìyàn tí kò bá pade rí ti wọn ba yọ ayọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ.
A tún rí gbọ wí pé orúkọ Darlington tí de iwájú gómìnà ipínlẹ̀ Anambra, latari òtítọ́ inú tó fi ń ṣíṣẹ.
0 comments:
Post a Comment