Ó ní ayajọ àwọn èwe lagbaye. Eléyìí sì. Mú mi rántí Musa, ọrẹ mi ìgbà èwe, ile iwe alakobẹrẹ láti pàdé.
Mo fẹ́ràn Musa nítorí wí pé o jẹ ọlọpọlọ pípé eniyan. Eyi si maa n je ki n ri gẹ́gẹ́ bi akanda eniyan kan.
Musa le má wà sí ilé ìwé fun odindi ọsẹ meji, igbakuugba to ba wu ko yọjú, ko si ibi to wu ka ti de lori isẹ kan ti a n bá a bọ̀, kò sí bi isẹ ohun selè le to loju wa, Musa yóò tun tayọ ju gbogbo wa lọ ni, koda ko jẹ asiko ìdánwò nikan lo yoju.
Orisii ọpọlọ Musa a maa ba mi lẹ́rù nitori mi o fi ibi kankan sún mọ́ ọ nibi isẹ ọpọlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé joojumọ lè mi n wa si ilé ìwé. A si maa wu mi ki n dabi Musa ọmọ Ibrahim.
Musa nikan kọ lo wu mi ki n jọ. Ọ̀kan lara awon ọ̀rẹ́ mi kan naa tun wa to tun fara pẹ ẹ , Hamzat.
Ki i se ọpọlọ pipe lo mu Hamzat wu mi. Sugbon mo fẹ́ràn Hanzat nipa ẹwà ara tó ní .
Ti wọn ba ni ọkùnrin rẹwà, ati ọjọ ti won ti bí mi sáyé mi ò ti ri iru ẹwà Hamzat ri. Hamzat mọ féfé, pupa rẹ si la kedere bi ọ̀yẹ́ là kárí ayé.
Irun orí rẹ a máa gbọn lẹ́úlẹ́ú bi o ba n rin lọ bi irun èèbó. (Omo Niger Republic ni iya re, ìran Fulani ni wọn; won si ni iya rẹ lo fi irun naa jọ).
Hamzat tun ni orísìí ohùn (voice) kan, to jẹ wí pé tí ó bá ń bínú, ìbínú kìí hàn nínú ohùn rẹ. Ki ohùn ènìyàn o tutu ko si maa si agbara ìbínú to le yi padà kúrò ni ipò rẹ.
Lónìí ile tó mọ , ọpọlọ Musa ò wúlò mọ, ẹwà ara Hamzat ti bajẹ. Ibanujẹ nla lo má n jẹ fún mi tí mo ba rántí àwọn ọrẹ ìgbà èwe mi.
Ìmọ̀ jẹ ohun to se kókó si ìgbésí aye ẹ̀dá. Ẹ̀bùn níní si tun jẹ́ ore-ọ̀fẹ́ lati ọdọ Ọlọ́run lati se apọnle ẹ̀dá fún igbega. Sugbon olubori ibẹ ni ìwà . Awon kan pe ni ìṣesí tabi ìhà. Ohun kan naa ni gbogbo re ja si.
Isesi eni lo maa n fi ìwà ọwọ ẹni hàn . Iwa ọwọ ẹni si ni ọpakutẹlẹ si ìhà ẹni sí ohunkóhun ti a ba gbe dani tabi dojú kọ láyé .
Bi Musa se ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpọlọ to fun ìwé kíkà , ìhà to ko si ẹ̀kọ́ rẹ pada sọ imọ re di akurẹtẹ. Ohun ti oluko ko wa laaarin wakati kan sẹ́yìn, àgàgà ti a ba jade lo sere ki a to tun pada si kilaasi, maa ti gbagbe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ti won ko wa. Bi Musa bá sá ni ilé ìwé fun ọ̀sẹ̀ méjì, ẹyọ wóró kan ẹ̀kọ́ to ti kọ seyin ko ni bọ sọnù ni ọpọlọ rẹ.
Igba meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo tun yara ikawe meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ka nigba naa. Musa o tun yara kan ka leemeji ri.
Emi pada wo ile iwe gírámà, Musa o le lọ. Won tun gbami wọlé si Ifafiti, Musa gbiyanju sugbon aṣọ o ba ọmọyẹ mọ́ .
O ku diẹ ka jade ile iwe alakobere ni Hamzat bẹ̀rẹ̀ si ni tẹle awon ọ̀rẹ́kọ̀rẹ́ ti won n jọ un mú imukumu. Igba ti mo wo ile iwe girama, Hamzat o le wọlé pẹ̀lú wa nitori wi pe igbó ti yi lori. O si ti bẹ̀rẹ̀ si ni wi kantankantan kiri. Ọkàn mi bàjẹ́.
Àwọn òbí rẹ mu lọ sẹ́yìn odi lati lọ tọju rẹ. Igba ti Hamzat yóò fi pada wa sile. Àwọ̀ ara rẹ̀ ti ṣì, ojú rẹ ti hun jọ bi ojú agbalagba, ọmọ pupa ti jona bi eyin apẹ akara, irun ori re ti rejẹ tan bi igba ogun jàlú,. Bakan naa ni gan-angangan ko kuro lara rẹ tan patapata.
Igba miiran yóò tutù bi omi inu amu. Bee ba n baa sọ̀rọ̀ ko ni wí ohunkóhun .
Igba mi si rèé , erin òdì ni o maa rin lẹ́nu . Hamzat ko riran ri ara rẹ̀ debi wi pe yoo se itoju ara re gẹ́gẹ́ bi o ti yẹ .
Musa ati Hamzat je ọ̀rẹ́ mi ìgbà kekere ti a jo lọ ile iwe kan naa ti a si tun jọ ń gbe ni adugbo kan naa. Bi o tile je wi pe ogún ọmọdé ò le sere fun ogún ọdún. Sibesibe, sebi ọjọ́ taa ba ri ara eni o ye a dun nu ni?
Hamzat ò da mi mọ mọ ọ lọ́jọ́ ti mo duro ki i, ti Musa ba ri mi a foju pamọ.
Mo padanu won ki i se nipa iku bi ko se nipa igbe aye won to lọ́júpọ̀ nipa iwa ati isesi won.
Kosi iru ọgbọ́n ti ẹ̀dá le wu ko ni laye, kosi iru ebun ti Edua oke le fi jinki eniyan, ko de si iru imọ to le wa latari eni, bi eniyan ba padanu iwa tabi ti isesi eni ba kudiẹ kaato tabi ti iha eni ba mẹ́hẹ, omoluabi iru eni bee ko le duro.
Orisii awon eniyan ti won ba pagede ninu iwa, abi isesi tabi iha ni Yoruba n pe ni omoluabi, eyi si je olubori fun ẹwà, ọgbọ́n ati ẹ̀bùn.
Musa ati Hamzat jẹ awon ọ̀rẹ́ mi ti mi o le gbagbe lailai. Musa padanu ọpọlọ pipe. Hamzat si sọ ayé rẹ nu lati mojesin.
Ẹyin abiyamọ, ẹ rí gbogbo ọmọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ yín. Ẹ gbìyànjú ohunkóhun láti rán wọn lọ́wọ́. Olaju tí mú ayé bajẹ ju ti àtẹ̀yìnwá wá lọ. Mo gbó wí pé àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wá nilẹ ẹ̀kọ́ gírámà báyìí. Ifipabanilo, àti àwọn idaran míì tí pò láwùjọ wá ju atẹyin wá lọ. Ojúṣe àwọn abiyamọ sì ni láti rí dájú wí pé àwọn ọmọ kò kó sínú panpe.
Ẹ ṣeun fún àkókò yin
Happy Children's Day
Hmmmmmm! Àkàkógbón fún àwon èwe wa
ReplyDelete